Ọlọ́pàá, Amotekun, ọlọ́dé àti OPC dáwọ́ jọ mú afurasí ajínigbé márùn-ún l'Ekiti

Aworan awọn afurasi ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Police Command/X

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, ti kede pe ọwọ ti tẹ afurasi ajinigbe marun-un lẹyin ti iṣẹlẹ ijinigbe meji waye lere wọn nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita loju opo ayelujara X rẹ, o ni ọwọ tẹ wọn lasiko ti awọn ọlọpaa, pẹlu ajọṣepọ Amotekun, OPC, àjọ NSCDC, ati awọn ọdẹ ibilẹ, yabo inu igbo.

O ni awọn wọ inu igbo to wa ni Oke-Osun, de Ikere, Igbo-Okah, titi de awọn igbo nla to wa nibi ti Iju ati Ikere ti paala.

"Lasiko akanṣe iṣẹ naa, ni ọwọ ti tẹ afurasi ajinigbe marun-un, ti orukọ wọn n jẹ Usman Jelili, Mohammed Bande, Abubakar Aliu, Isah Abdulahi ati Suleiman Abdulahi.

Awọn afurasi naa sọ pe darandaran ni awọn, nigba ti a n fi ọrọ wa wọn l'ẹnu wo, ṣugbọn aṣiri pada tu pe ko si eyikeyi ninu wọn to ni ẹran ọsin kankan,'' ileeṣẹ ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkada meji, ada kan, ọ̀bẹ aṣóró kan, ati foonu mẹrin, ni awọn ba lọwọ wọn.

Ọjọ Aje ni awọn agbebọn pa ọba ilu meji nipinlẹ Ekiti.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awon Ọba meji naa ni, Onimojo ti Imojo Ekiti, Oba Olatunde Samuel Olusola ati Elesun ti Esun Ekiti, Oba David Babatunde Ogunsola.

Awon ori ade yii lawọn agbebon naa sekupa nigbati wọn n pada bọ lati ipade lobaloba ti wọn lọ ṣe niluu Irele-Ekiti.

Yatọ si iku awọn ọba naa, ọjọ Iṣẹgun ni iroyin tun jade pe awọn ajinigbe da ọkọ ile ẹkọ aladani kan lọna, ti wọn si gbe awọn akekọọ ati olukọ lọ.

Akẹkọọ mẹfa ati olukọ mẹta ni wọn ji gbe ni irọlẹ ọjọ Aja ni ijọba ibilẹ Emure, lasiko ti wọn n pada sile.