Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ yẹgi fún ọkùnrin tó fi ọmọ odó pa mọ̀lẹ́bí rẹ̀ l’Ekiti

Oríṣun àwòrán, Sang Hyun Cho/Pixabay
Ile ẹjọ giga kan niluu Ado Ekiti ti ṣe idajọ iku fun ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kàn, Sunday Arowolo, lẹyin to jẹbi ẹsun ipaniyan.
Ọjọ karun un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni ọkunrin naa kọkọ foju bale ẹjọ lori ẹsun pe o pa mọlẹbi rẹ kan, Arowolo Dare.
Ile ẹjọ sọ pe ohun ti ọkunrin naa ṣe lodi si abala 391(1) iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ekiti ti wọn gbe kalẹ lọdun 2012.
Ọmọ oloogbe naa sọ ninu akọsilẹ rẹ ni agọ ọlọpaa pe ṣe ni afurasi naa fi panpẹ kan de ọwọ baba oun, ko to la ọmọ odo mọ ori ati aya rẹ.
O ni "Mo gbiyanju lati yọ panpẹ naa ṣugbọn ọwọ mi o ka.
"Sunday Arowolo pada wa pẹlu igi to fẹ là mọ mi ṣugbọn o ṣubu nibi to ti n le mi ki n to sa wọ abule kan fun iranlọwọ.
"Lẹyìn naa ni mo lọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ẹbi wa leti, wọn gbe alupupu wa lati gbe baba mi lọ sile iwosan nibi to dakẹ si."
Agbẹjọro ìjọba, Oluwaseun Olasanmi pe ẹlẹri meje ọtọtọ tako afurasi naa pẹlu awọn ẹri miran.
Bẹẹ naa ni agbẹjọro Arowolo sọrọ lorukọ rẹ lati sọ ipa to ko ninu iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, ilẹ ẹjọ da ẹjọ iku fun Arowolo.
Adajọ ni ki wọn lọ yẹ igi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.














