Ìjọba, ẹ fún wa ní ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ l'Ekiti láti lè kójú ìṣòro ètò àbò, àwọn ọba ké gbàjarè

Aworan alaga igbọmọ lọbalọba Ekiti

Oríṣun àwòrán, Biodun Oyebanji/Facebook

Àwọn igbimọ lọba lọba nipinlẹ Ekiti ti rọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ ti beere fun aṣẹ lọwọ ijọba apapọ ati ìjọba ipinlẹ lati le maa daabo bo agbegbe wọn lati iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ lera wọn.

Ọba Ayorinde Ilori, Olojudo ti Ido-Ekiti to tun jẹ Alaga fun gbogbo awọn Ọba nipinlẹ Ekiti tun kepe ijọba lati ṣe ifilọlẹ ọlọpaa ipinlẹ lati koju iṣoro eto abo to mẹhẹ nipinlẹ naa.

Ọrọ yii lo waye lakoko ti awọn lọba lọba ṣe ipade pọ pẹlu Gomina Abiodun Oyebanji ati awọn ẹsọ alaabo gbogbo nipinlẹ Ekiti ni Ọjọru.

Ọba Ayorinde Ilori tun kepe ìjọba apapọ labẹ isejoba Bola Ahmed Tinubu,lati fun awọn ni ase lati ni Ọlọpaa ibile nipinlẹ Ekiti, nitori ọlọpaa ijọba nikan ko to fun eto abo nipinlẹ Ekiti rara.

Ori-ade naa sọ pe awọn ajinigbe ti pọju ní orilẹ-ede Naijiria papa ju lọ ni ipinle Ekiti.

Gomina Oyebanji ninu ọrọ rẹ, ba ẹbi ati awọn igbimọ lọba lọba nipinlẹ Ekiti kẹdun lori isẹlẹ laabi to sẹlẹ lera wọn.

Gomina Oyebanji tun ka ọrọ ti Aarẹ Tinubu fi ransẹ si awọn igbimọ lọba lọba nipinlẹ Ekiti fun lori awọn akẹgbẹ wọn tawọn janduku agbebọn ṣekupa.

Aworan alaga awọn ọba Ekiti ati gomina
Aworan awọn lọbalọba Ekiti
Aworan awọn lọbalọba Ekiti

O ni aare ki gbogbo ipinle Ekiti paapaa julọ awọn lọba lọba nipinlẹ naa pe, wọn ku ara fẹra ku.

Gomina ipinlẹ Ekiti sọ fun gbogbo awọn ọba nipinlẹ naa pe, iwadii n lọ lọwọ lori Isẹlẹ naa.

Gomina wa beere fun ifowosowopo ara ilu paapa julọ awọn lọba lọba lati gba awọn ẹsọ alabo laye lati ṣe iwadii wọn.

Gomina Oyebanji wí pe ''mo mọ pe asiko yii jẹ asiko ibanujẹ fun gbogbo wa nipinlẹ Ekiti.

Sugbọn mo fẹ kẹ gba awọn eleto abo laye gidigidi lati se isẹ wọn fun iwadii to peye.''

Lẹyin ti Gomina sọrọ rẹ tan ni gbogbo awọn igbimọ lọba lọba gboriyin fun Gomina Oyebanji pe o jẹ asiwaju rere

Wọn tun pàrọwà fun Gomina Oyebanji lati gba awọn ẹsọ alaabo ti ibilẹ naa laye lati dara pọ pẹlu awọn ẹsọ alabo ti ijọba.

Gómìnà pàṣẹ fáwọn ẹ̀ṣọ́ elétò àbò láti ṣàwárí àwọn ajínigbé tó pá Ọba Ekiti méjì

Aworan awọn ọba Ekiti

Oríṣun àwòrán, Other

Gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Oyebanji ti bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu buruku to waye ni ọjọ Aje ni agbegbe Oke-Ako ni ijọba ibilẹ Ikole, eyi ti o fa iku awọn Ọba Ori-Ade méjì.

Gomina Oyebnaji ti wa paṣẹ fun awọn ile-iṣẹ eleto abo ni ipinlẹ Ekiti lati ṣawari awọn onise ibi naa.

Awon Ọba meji naa ni, Onimojo ti Imojo Ekiti, Oba Olatunde Samuel Olusola ati Elesun ti Esun Ekiti, Oba David Babatunde Ogunsola.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awon ori ade yii lawọn agbebon naa sekupa nigbati wọn n pada bọ lati ipade lobaloba ti wọn lọ ṣe niluu Irele-Ekiti.

Amọ, ori ko Oba Adebayo Fatoba ni Ori-Ade kẹta, Alara ti Ara–Ekiti, yọ ninu ikọlu ibi naa.

Gomina Oyebanji, ti o sese pari ipade igbimo eto aabo ipinle naa niluu Ado-Ekiti, ni nnkan bii wakati kan ki isele naa to waye, so pe gbogbo ipa ni ijọba yoo sa lati ri pe ọwọ tẹ awon odaran naa.

Gomina si tun kedun pelu awon awon ara ilu Imojo Ekiti ati Esun Ekiti lori isele ibanuje naa.

O tun ro awon ara ilu mejeeji lati fara bale, lati ma fi ibinu ṣe idajo lọwọ ara wọn pe ijoba yoo rii daju pe idajọ ododo waye.

Gomina ipinlẹ Ekiti tun paṣẹ fun awọn ajo eleto aabo ni ipinle Ekiti lati tunra mu ki wọn si ṣọra ​ ninu akitiyan lati dẹkun ijamba ibi ati iwa odaran ikọlu ojiji kuro ni ipinle naa.

Gomina ni ijọba oun yoo tubọ ma mu eto aabo to peye, ati igbe aye irọrun awọn ara ilu ipinlẹ Ekiti ni ọkunkundun.

Gomina sọ pe iṣakoso oun yoo tẹsiwaju lati fi imọ-ẹrọ igbalode se atilẹyin fun awọn ile-iṣẹ eto aabo ni ipinlẹ Ekiti.