Ẹnìkan ló fi fọ́nrán ìròyìn eré ìdárayá mi sórí ayélujára tí àwọn èèyàn fi tẹ́wọ́ gbà á - Olori Sport

Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye, bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu bi gbajugbaja akaroyin ere idaraya, Aderonke Adesola tawọn eeyan mọ si Olori Sport.
Odu ni Aderonke nibi ki a ka iroyin ere idaraya pẹlu ẹwa ede Yoruko.
Aderonke sọ fun BBC Yoruba wi pe ''igba ti awọn ọga mi ri pe mo ni ẹbun lati maa ka iroyin ere idaraya, nigba naa ni mo mọ pe akoko ti to fun mi lati gbera.''
Amọ, o ṣalaye pe ẹnikan lo fi fọnran iroyin ere idaraya ti oun sẹ sori ayelujara to wa di pe gbogbo awọn eeyan tẹwọ gba a.
O ni oun gẹgẹ bi ẹnikan, oun ko nifẹ si lilo ayelujara tẹlẹ.
''Ile ti mo ti jade wa, ile ti wọn ti nifẹ ere idaraya ni, wọn yan ere idaraya laayo, bo tilẹ jẹ pe awọn obi mi ko maa gba a jẹun.
Ibi ti mo ti wa, ile alaṣa, ile elede ni, ọmọ o gbọdọ ti ati Bere Bode, Molete, Popo wa ki o wa ma si awọn lamba ijinlẹ ọrọ lẹnu rẹ.
Nigba ti awọn ọga mi ri pe mo ni ẹbun lati maa ka iroyin ere idaraya, nigba naa ni mo mọ pe akoko ti to fun mi lati gbera,'' Aderonke ṣalaye.
Aderonke ni ''ibi ti mo ti kọkọ bẹrẹ iṣẹ igbohunsafẹfẹ gẹgẹ bi akaroyin ere idaraya ni ọga mi ti fun mi ni orukọ Olori Sport, bo tilẹ jẹ pe ọga mi naa kọ lo kọ mi ni iṣẹ yii ni ṣan an san an.
Nile ti mo dagba si, ti o ba tẹle Barca awọn Sapalona wa a maa tẹle Chelsea awọn ọmọ iya alaro.
Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni mo nifẹsi julọ tori ẹgbọn mi ti mo nifẹ si julọ ti Chelsea ni wọn n ṣe
Bo tilẹ jẹ pe mo n kabamọ rẹ pe awọn ọmọ iya alaro ti wọn n gbe labẹ Bridge awọn ni mo n tẹle.''






