A ti mú ọmọ Ọba Eniola Oyeyode tó pàṣẹ fún Hammed Abdul Jelili láti yìnbọn ní Ejigbo- Ọlọ́pàá

@Ade ori kin

Oríṣun àwòrán, @Adeori okin

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Oṣun ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti mu Ọmọ Oba Eniola Oyeyode si gbaga wọn.

Oga ọlọpaa ni Oṣogbo ṣalaye pe àwọn ẹṣọ alaabo si ti gbebón fun Ahmed Abdul Jelili to ṣeṣi yinbọn pa Oloogbe Ade Ori ọkin ni ilu ejigbo ni ipinlẹ Osun.

Awọn ara Ejigbo sọ pe ọmọ ọba Eniola sọ pe oun ni ki ẹṣọ oun, Abdul Jelili Hammed yinbọn soke lati fi wo ọta ibọn rẹ ṣugbọn oun ko mọ bi ibọn naa ṣe lọ ba Omowe Richard to wa sile lati America.

Lẹsẹkẹse ni Hammed Abdul Jelili dagbere fun aye ti Dokita ile iwosan si sọ pe Ade ori ọkin ti ku ki wọn to gbe e de ile iwosan.

Omo oba Oyeyode Eniola ni awọn agbofinro sọ pe a\won n fi ọrọ wa lẹnu wo bayii.

Saaju ni Ọmowe Richard Ade ori ọkin ti wa sile lati America wa ba Oba Oyeyode ṣe ayẹyẹ ọdun aadọta lori itẹ ki o to jẹ Olorun nipe lalẹ ọjọ ayẹyẹ naa nipase àṣìta ibọn lati ọdọ ẹṣọ ọmọ ọba to n sẹ ayẹyẹ aadọta ọdun lori apere baba rẹ,

Aworan Richard Idowu

Oríṣun àwòrán, drrichard_idowu/Instagram

Ta ni Ọ̀mọ̀wé Richard Idowu Adeori Okin tí ìbọn ẹ̀ṣọ́ ọmọba Ejigbo pa l’Osun?

A bi Ọmọwe Richard Idowu ti ọpọ mọ si Adeori Okin si idile Onimọ-ẹrọ ati Arabinrin Ademola Idowu ni agbo ile Alabi Liasu niluu Ejigbo, ni ipinlẹ Osun.

O lọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ile ẹkọ NEPA Staff School, Egbin, Ikorodu, ni ipinlẹ Eko.

Ọmọwe Idowu tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Oriwu Model College niluu Ikorodu bakan naa.

Ile ẹkọ giga fasiti Ilorin, UNILORIN ni Richard ti kẹkọọ gboye ninu imọ Iṣiro.

Ifẹ ti o ni si eto ẹkọ lo mu lọ si oke okun nibi to ti gboye keji ni fasiti Louisiana State University, l’Amẹrika nibi to ti gboye M.Sc lọdun 2009 ninu imọ Iṣiro.

Nile ẹkọ fasiti ipinlẹ Louisiana ni America yii kan naa lo ti bẹrẹ ẹkọ lati di Ọmọwe ninu imọ Iṣiro lọdun 2012.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluwadii onimọ ijinlẹ fun igba diẹ ni fasiti kan naa yii lẹyin to gba oye Ọmọwe rẹ tan.

Nigba to fi jẹ akẹkọọ nile ẹkọ giga ipinlẹ Louisiana, o ṣiṣẹ lori oniruuru iwadii eleyii ti o tẹ jade ninu iwe iroyin.

O ti fẹ di Ọjọgbọn tan ninu imọ Iṣiro ni ile ẹkọ giga Praire View A & M University, Houston Texas, l’Amẹrika.

O si ti wa ni ipo yii lati ọdun 2016.

O ti kọ ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ giga Louisiana Tech University & Praire View A & M University.

Gomina Ipinlẹ Osun paṣẹ iwadii iku Richard Adeori Okin ati ọlọdẹ to pa a

Aworan Adeori Okin

Oríṣun àwòrán, Richard Idowu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti paṣẹ iwadii iku to pa Ọmọwe Richard Idowu Adeori Okin ati ẹṣọ ti oun naa di oloogbe nibi ayẹyẹ aadọta ọdun ti Ogiyan ti ilu Ejogbo, Oba Omowonuola Oyeyode Oyeyosin gori itẹ.

Gomina kẹdun pẹlu awọn eeyan ilu Ejigbo lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi sita, Adeleke paṣẹ wi pe ki awọn agbofinro bẹrẹ iwadii ni kiakia lati mọ ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ iṣekupani naa.

Bakan naa ni gomina tun paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto abo lati ri pe rogbodiyan ko bẹ silẹ niluu Ejigbo lẹyin iṣẹlẹ yii.

Adeleke tun rọ awọn ẹbi awọn to ku naa ki wọn maa gbiyanju lati ja fun ara wọn, ki wọn ṣi ma ṣe ohun to lodi si ofin.

Gomina ipinlẹ Osun tun wa gbe igbimọ kan dide lati lọ ṣe abẹwo si ilu Ejigbo latari ohun to ṣẹlẹ nibẹ.

Awọn to wa ninu igbimọ naa ni kọmiṣọna ọlọpaa, kọmiṣọna to n ri si ọrọ oye ati ijọba ibilẹ, awọn mii to wa ninu igbimọ ọhun ni kọmiṣọna eto iroyin ati oludamọran gomina lori eto abo.

Gomina Adeleke ni ‘’ohun to ṣẹlẹ niluu Ejigbo bani lọkan jẹ gidi gan an.

Mo kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn to ku. Yatọ si aṣẹ ti mo pa wi pe kawọn agbofinro ṣe iwadii ohun to ṣe okunfa iku Ọmọwe Richard Adeori Okin ati iku ọlọdẹ to yinbọ pa a, mo tun ti sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati kede ilana lori lilo ibọn ibilẹ.

Ilana yii yoo ṣe iranwọ nipa eto abo awọn araalu papaa julọ nibi ti ayẹyẹ kan tabi omiran ba ti n waye lawujọ.’’

Ọlọ́pàá ti mú ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ tó yìnbọn pa Adeori Okin l'Osun

Ileeṣẹ ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Osun ti sọrọ lórí ikú tó pá Ọgbeni Richard Idowu tawọn eeyan mọ si Adeori Okin l'Ọsun.

Arabinrin Yemisi Opalola to jẹ agbenuso fun awọn Ọlọpaa ipinle Osun ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni deede agogo mẹsan an alẹ ọjọ Abamẹta ni kete ti wọn pari ayẹyẹ aadọta ọdun ti Ọba Oyeyode Oyesosin Ogiyan ti ilu Ejigbo gun ori apere awọn baba nla rẹ.

Opatola ni ''igbayi ni ọkan lara Ọmọ ọba Oyeyode Oyesosin ti orukọ rẹ njẹ Ọmọ Ọba Eniola Oyeyode pasẹ fun ọkàn lara awọn ẹsọ to wa lẹyin rẹ pe, ko yín ìbọn ẹlẹnu meji to wa lọwọ rẹ soke lati le mọ bi ọta inu ìbọn naa dara.

Eyi ni Hammed Abduljelili ẹni to jẹ ọkan lara ẹsọ fun ọmọ Ọba naa se to fi kọju ìbọn naa si Richard Idowu ti o si gba ibẹ ku.

Wọn sare gbe Idowu lọ sile iwosan kan to sun mọ tosi agbegbe naa, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Sugbọn bayi, Ọmọ Ọba Eniola Oyeyode ti wa ni kolo awọn Ọlọpaa ipinle Osun bayi fun iwadi to peye.''

Arabinrin Opalola wa fi ọrọ ti Komiṣọna Ọlọpaa nipinle Osun CP Bzigu Dali Kwazhi ransẹ pe, ki gbogbo ipinle Osun papaa julọ olugbe ilu Ejigbo ti iṣẹlẹ yii ti waye lọ fi ara balẹ lori Isẹlẹ naa.

O ni iwadii ń lọ lọwọ lori rẹ ati pe, idajọ ododo yoo fara han lori iku to pa Richard Idowu.

Maapu Osun

Oríṣun àwòrán, @Osun

Ọlọpaa yinbọn pa ẹṣọ pa Idowu Adeori Okin l'Osun

Agbenuso fun awọn Ọlọpaa ipinle Osun sọ pe lẹyin ti ibọn ba Adeori Okin tan ni ẹṣọ to yinbọn ọhun ki ere mọlẹ lati ma sa lọ.

O ni eyi lo mu ki awọn Ọlọpaa mura lati le e ri mu sugbọn ninu igbiyanju awọn ọlọpaa lati le ri afurasi naa mu lo ja si iku fun un latari bi ó se doju ija kọ awọn ọlọpaa naa.

Komiṣọna fun eto iroyin nipinle Osun, Kolapo Alimi ti ba gbogbo ọmọ ipinle Osun paapa julọ awọn olugbe ilu Ejigbo sọrọ lati fun awọn Ọlọpaa laye fun iwadi to peye lori isẹlẹ naa.

Arakunrin Alimi tun fi kun ọrọ pe gomina Ademola Adeleke ti ba awọn ẹsọ alabo nipinlẹ Osun sọrọ lati se iwadii to daju lori iku Ogbeni Idowu.

Adeori Okin jẹ oloselu ninu ẹgbẹ APC tẹlẹ ko to kuro lọ sinu ẹgbẹ Oselu PDP.

Richard Idowu jẹ olukọ ni Fasiti kan ni orile-ede Amerika.

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, @Osun Govt

Àkọlé àwòrán, Adeleke Ademola Gomina