Mọ́ nípa ìdí tí Mali, Niger àti Burkina Faso ṣe fi ECOWAS sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀ èdè Mali, Niger àti Burkina Faso ti kéde ìpinnu wọn láti kúrò nínú àjọ Economic Community of West Africa States (ECOWAS).
Nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2024 ni wọ́n ti kéde ìpinnu yìí.
Bákan náà ni wọ́n tún ka ìpinnu wọn yìí lórí iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan ní orílẹ̀ èdè Niger Republic.
Àwọn olórí orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní ìpinnu àwọn náà yóò jẹ́ mímúṣẹ lẹ́yẹ ò sọ́ka.
Wọ́n ní àwọn pinnu láti fi ECOWAS sílẹ̀ nítorí àjọ náà ti yàtọ̀ sí nǹkan tí àwọn babańlá àwọn gbèrò kí wọ́n tó dá àjọ ọ̀hún sílẹ̀.
Wọ́n ṣàlàyé gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ àti ètò tí àwọn tó dá àjọ náà sílẹ̀ fojúsùn ni kò jẹ́ mímúṣẹ mọ́, pé nítorí náà ni àwọn ṣe panupọ̀ láti fi àjọ ọ̀hún sílẹ̀.
Wọ́n ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ̀ fún àwọn pé lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀, ìrètí àwọn tó da sílẹ̀ kò wá sí ìmúṣẹ.
Agbẹnusọ ìjọba ológun Niger, Colonel Amadou Abdramane nínú àtẹ̀jáde ní àjọ náà kò ran àwọn lọ́wọ́ láti gbógunti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí àti àìsí ètò ààbò tó ń bá àwọn orílẹ̀ èdè náà fínra.
Nínú oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 ni àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tọwọ́bọ àdéhùn láti máa ran ara wọ lọ́wọ́ láti kojú ìpèníjà kankan tó bá dojú kọ wọ́n.
Ìbáṣepọ̀ náà tún túmọ̀ sí lílo àwọn ọmọ ogun láti kojú ìṣòro tó bá dojú kọ wọ́n.
Ṣáájú ni ECOWAS ti fòfin de àwọn orílẹ̀ èdè yìí lẹ́yìn tí àwọn ológun dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ àwọn alágbádá.
Ìpinnu wọn láti fi ECOWAS sílẹ̀ yóò nira fún àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti kàn-án nípa fún àwọn ológun lórílẹ̀ èdè náà láti gbé ìjọba padà fún àwọn alágbádá.
Nínú ọdún yìí ni ìrètí wà pé wọn yóò ṣètò ìdìbò láti gbé ìjọba fún àwọn alágbádá.
Niger, Mali àti Burkina Faso kò kọ̀wé sí wa pé àwọn ti fi àjọ náà sílẹ̀ – ECOWAS

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí àwọn orílẹ̀ èdè kéde pé àwọn ti fio ECOWAS sílẹ̀ ni àjọ náà kéde pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa ìpinnu yìí.
ECOWAS nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta ní Niger, Mali àti Burkina Faso kò kọ̀wé láti fi tó àwọn létí pé àwọn kò sí nínú àjọ náà mọ́.
Wọ́n ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí orílẹ̀ èdè yìí láti ri pé wọ́n dá ìjọba padà sí ètò ìjọba àwaarawa àti pé ipò wọn nínú ECOWAS kò kéré rárá.
Wọ́n ní àwọn máa tẹ̀síwájú láti ri dájú pé àti ní àjọsọ láti wá ojútùú sí wàhálà tó ń wáyé lágbo òṣèlú orílẹ̀ èdè náà.














