Ọlọ́pàá Hisbah mú awakọ̀ Maruwa 53 lórí pé wọ́n gẹ irun tí kò bójúmu, fi ṣòkòtò péńpé ṣiṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ọlọpaa Hisbah nipinlẹ Kano ti fi ṣikun ofin mu awakọ kẹkẹ Maruwa mejilelaadọta lori ẹsun pe wọn gẹ irun to lodi, wọn n ta ooogun oloro ati pe wọn n gbe obinrin pọ mọ ọkunrin ninu kẹkẹ wọn.
Awọn awakọ kẹkẹ naa, ti wọn n pe ni ‘Yan Adaidaita Sahu’ ni wọn mu kaakiri ilu Kano, to jẹ olu ilu ipinlẹ ọhun.
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ikọ agbofinro ọhun bẹrẹ eto kan ti wọn pe ni “Operation Kau da Badala,” eyii ti wọn ni awọn yoo fi fọ ipinlẹ naa mọ lọwọ iwa nọbi, ọti mimu, oogun oloro lilo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igbakeji adari ikọ Hisbah ni Kano, Sheikh Mujahid Aminuddeen to ba awọn awakọ naa sọrọ ni “a fẹ lo akoko yii lati rọ yin lati yago fun awọn iwa to le ba orukọ ẹsin ati aṣa ipinlẹ Kano jẹ.”
O fi kun pe lara ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa ni wiwa kẹkẹ wọn laarin igboro pẹlu ṣokoto penpe.
Aminuddeen tun fi ẹsun kan wọn pe wọn n lẹ awọn aworan ti ko tọ mọ ara kẹkẹ wọn ati pe wọn n ko ero to jẹ ọkunrin ati obinrin sinu kẹkẹ kan naa.
Ko tan sibẹ, Hisbah sọ pe awọn afurasi naa n ta oogun oloro, wọn tun n fi kẹkẹ wọn gbe awọn obinrin lọ sibi ti wọn ti n ṣe iṣekuṣe.
O ni “Gẹgẹ bii Musulumi, a ko ni tẹwọgba iwa ti awọn awakọ kẹkẹ yii n wu.
“Idi ree ti a fi ko yin wa sibi lonii lati da yin lẹkọọ nipa atubọtan ohun ti ẹ n ṣe lara ẹsin ati aṣa wa ni Kano.”
A gbọ pe lẹyin ti Hisbah ba awọn eeyan naa sọrọ tan ni olu ọọfisi rẹ, o fi wọn silẹ ki wọn maa ba tiwọn lọ.

























