Mo ṣetán láti kú pẹ̀lú Portable tó bá kó ààrùn látara obìnrin mìíràn - Ashabi

Oríṣun àwòrán, @Ashabi_simple/INSTAGRAM
Ọkan ninu awọn obinrin to bimọ fun akọrin Zazu, Portable ọmọ Ọlalọmi, Ọmọbọlarinde Akinyanju tawọn eeyan mọ si Aṣabi, ti sọ pe oun ṣetan lati ku pẹlu olorin naa to ba lugbadi arun ko-gboogun.
Lori eto kan ti gbajumọ ọsere, Biọla Adebayọ maa n ṣe ni Aṣabi ti sọrọ yii to si ti n ja ran-in lori ayelujara.
Aṣabi toun naa jẹ oṣere tiata to ṣẹṣẹ n goke agba, sọ pe, ‘’ Lọkan mi, emi nikan ni Portable fẹ.
O ni lọkan toun, oun nikan ni iyawo ti Portable fẹ ati pe oun kii figba kan ro o pe boya ọdọ obinrin miiran lo wa nigba ti ko ba si pẹlu oun.

Oríṣun àwòrán, @Ashabi_simple/INSTAGRAM
"Mo mọ pe o lobinrin pupọ lọwọ, to ba jade lọ, mo gbagbọ pe o lọ wa ohun ta a maa jẹ ni.
"To ba ti de pada, mo gbagbọ pe emi nikan lo de fun.
Bakan naa lo tun sọró lori bi awọn obinrin mii ṣe maa n ni awọn ko le fẹ ọkunrin to ba ni iyawo kan tabi to n yan ale nitori aarun.
Ashabi ni oun maa n gbadura pe Ọlọrun ko ni jẹ ki o lugbadi aarun kankan amọ ọrun n yabọ ni ọrọ naa kii ṣe ti ẹnikan.
O ni oun mọ pe ti o ba lọ ko aarun gbogbo awọn ni awọn jọ maa pin ninu rẹ ati pe kii ṣe oun nikan ni iya rẹ yoo jẹ.
O fi kun pe oun ti pa ọkan oun pọ pe ti iru rẹ ba ṣẹlẹ, gbogbo awọn ni awọn jọ maa jiya rẹ ati pe to ba jẹ eyi to ba maa mu ẹmi lọ naa ni, awọn mejeeji ni awọn jọ maa ba lọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"K’Ọlọrun ma jẹ ko ko arun, to ba dẹ ko eyi to le mu iku wa, a jọ maa ku pọ naa ni’’
Ọmọbinrin yii ṣalaye, pe loootọ loun ki i ṣe aayo ninu awọn iyawo Portable, ṣugbọn o maa n fifẹ han soun daadaa.
Ipo kẹrin ni Ọmọbọlarinde Aṣabi wa, ninu awọn obinrin to bimọ fun Portable olorin Zazu.
Awọn mi-in tun ni Ẹwatomi Ọmọbẹwaji, Honey Berry ati bẹẹ bẹẹ lọ.














