Òkú Sylvester Oromoni wọ káà ilẹ̀ sùn lẹ́yìn ọdún méjì tó kú

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ṣe ẹ ranti ọmọkunrin ẹni ọdun mejila nni, Sylvester Oromoni Jnr to ku lojiji lọdun 2021 nileewe Dowen College, ti iku ọhun si di ariwo gidi lori ayelujara?
Oku ọmọ naa ti wọ kaa ilẹ sun lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kin-ni-ni ọdun 2024 yii.
Ile ẹbi Oromoni to wa ni Ogbe-Ijoh, nijọba ibilẹ Guusu Warri, ipinlẹ Delta ni wọn sin Sylvester si lẹyin ọdun meji ti awọn eeyan rẹ ti n beere fun idajọ ododo lori iku ọmọ naa.
Ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Sylvester Oromoni dagbere faye, awuyewuye to si tẹle iku naa ni pe awọn akẹkọọ agba kan ni Dowen College ni wọn fiya jẹ ẹ de oju iku.
Ọpọ awọn ajafẹtọo ọmọniyan, awọn obi, ẹbi, ọrẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n sunkun asun-un-dakẹ bi wọn ṣe gbe posi ọmọ ọdun mejila naa de, ti wọn si gbe e si koto lẹyin ọdun meji to ti dagbere faye.
Fẹmi Falana gboriyin fun Sylvester, o ni igbesi aye rẹ lapẹẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Punch
Agba ọjẹ agbẹjọro, Femi Falana naa wa lara awọn to peju pesẹ sibi eto isnku ọmọ naa.
Falana sọ pe bo ṣe jẹ pe ọdun perete lọmọ naa lo laye, sibẹ, apẹẹrẹ rere lo fi lelẹ nileewe, ninu ẹbi ati laarin awọn ẹgbẹ rẹ.
‘Ọdun diẹ ti Solomon lo laye, a o le fi we ti Methuselah to pẹ titi. Sylvester ni ipa rere lori awọn olukọ rẹ, awọn ọrẹ ati ẹgbẹ rẹ nileewe.
Amofin agba Fẹmi Falana, to wa nibi eto isinku naa, gboriyin fun Oloogbe Sylvester Oromoni loju iku.
‘’Ohun ti a gbọdọ maa ran ara wa leti ni pe ki la fẹ kaye fi ranti wa ta a ba lọ tan. Ka si dari aye wa pada sọdọ Oluwa to da wa.
‘’Mo dupẹ lọwọ awọn obi Sylvester, bi wọn ṣe duro fun idajọ ododo’’
Ṣaaju ni baba ọmọ naa ti jẹjẹẹ pe oun ko ni sin oku ọmọ ọhun bi oun ko ba ri idajọ ododo gba lori iku ọmọ oun amọ awọn ọlọpaa ni iwadii oku ọmọ naa ti wọn ṣe ko fi han pe ẹnikankan lo pa a.
Mọ́lẹ̀bi kéde ètò ìsìnkú Sylvester Oromoni lẹ́yìn ọdún méjì tó kú

Oríṣun àwòrán, BBC/SYLVESTER OROMONI
Ọdun meji lẹyin iku ọmọ ọdun mejila Sylvester Oromoni, awọn mọlẹbi rẹ ti kede bi eto isinku yoo se waye.
Ọgbọnjọ oṣu kọkanla, ọdun 2021 ni iroyin sọ pe Sylvester ku, nile ẹkọ Dowen College, lẹyin ti awọn akẹkọọ to wa ni ipele to ga fi iya jẹ ẹ nitori o kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Ninu atẹjade ti ẹbi fi sita, wọn kede pe eto isinku naa yoo waye lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2024 nipinlẹ Delta.
Wọn fikun pe pẹlu bi iroyin iku ọmọ wọn se gba ori ayelujara, o bawọn lọkan jẹ pe wọn ko ti ri idajọ ododo gba lori isẹlẹ naa.
Atẹjade ọhun sapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ọmọ ti oye rẹ pe pupọ, to si wu lọkan lati mọ si nipa ero ayarabiasa ati ere bọọlu.
Saaju ni iroyin jade pe baba ọmọ naa ni oun ko ni sin ọmọ naa ti oun ko ba ri idajọ ododo gba.
O sọ eyí lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ naa, eyi ti wọn ṣe lati ṣẹyẹ ọdun mejila ti o yẹ ki o se ki o to ku lọdun 2021.
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori isẹlẹ yii?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọrọ ninu oṣu Kinni, ọdun 2022 pe ko si ẹri to daju lati fidi rẹ mulẹ pe, awọn kan lo lu akẹkọọ ile ẹkọ Dowen ọhun, Sylvester Oroomoni ki ẹmi to bọ lẹnu rẹ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko tẹlẹ, Hakeem Odumosu ṣalaye fawọn akọroyin pe ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe wọn fipa fun Sylvester ni kẹmika mu ki o to ku.
Odumosu ni esi ayẹwo oku ti wọn ṣe lara oku Sylvester fihan pe iku ati ọdọ Ọlọrun wa ni akẹkọọ ọmọ ọdun mejila naa ku.
Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe ko si ẹri bakan naa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹẹgbẹ Sylvester kan fẹ ẹ fi ipa mu wọ ẹgbẹ okunkun.














