Owó tí mò ń rí nídìí iṣé jórinmọ́rin ju èyí tí mò ń pa nídìí iṣẹ́ ‘lecturer’ lọ – Ọjọgbọn

Zaira

Oríṣun àwòrán, Mansur Abubakar

Ọjọgbọn fasiti ni Kabir Abu Bilal niluu Zaria, nipinlẹ Kaduna, amọ o tun n ṣiṣẹ jorinmọrin lẹgbẹ kan.

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe iṣẹ awọn ti ko kawe ni iṣẹ jorinmọrin jẹ, amọ iyalẹnu nla lo jẹ fun awọn akẹgbẹ Bilal nigba ti wọn gbọ pe o ni ṣọọbu jorinmọrin.

Kii kan n ṣe pe o ṣi ṣọọbu naa lasan, oun funra rẹ jẹ ogbontarigi ajorinmọrin.

Ọkunrin naa, to jẹ ẹni aadọta ọdun n kọ awọn akẹkọọ ni imọ ẹrọ nile ẹkọ Ahmadu Bello University, niluu Zaria.

O ti ṣiṣẹ fasiti naa fun ọdun mejidinlogun nibi to ti kọ oniruru akẹkọ nipa imọ physics ati electrical engineering.

Nigba ti oun furan rẹ n ba BBC sọrọ, Bilal sọ pe oju kii ti oun lati ṣiṣẹ naa.

O ni “Ko ti mi loju lati maa ṣiṣẹ ajorinmọrin bo tilẹ jẹ pe Ọjọgbọn ni mi ni fasiti.

“Owo ti mo n pa nidi iṣẹ jorinmọrin pọ ju eyii ti mo n ri nidi iṣẹ olukọ fasiti lọ.”

Akẹgbẹ rẹ kan to ba BBC sọrọ, Yusuf Jibril, ni o ya awọn lẹnu pe o n ṣiṣẹ ajorinmọrin.

Jibril sọ pe “Ohun to n ṣe kii ṣe ohun itiju rara, koda, iwuri lo jẹ fun awọn akẹgbẹ rẹ.”

Ọjọgbọn Abu Bilal ni ẹkọ nla lo ye ko jẹ fun awọn ọdọ to ṣẹṣẹ n kẹkọọjade nipa bi eeyan ṣe le wa ounjẹ oojọ rẹ.

“Iwe kika ko sọ pe ki eeyan ma ṣe iru iṣẹ bayii, iyalẹnu lo maa n jẹ fun mi nigba ti mo ba ri awọn to ni BSc pere ti wọn ba n foju tẹmbẹlu iru iṣẹ bayii.”

Atẹjade kan lati ọọfisi ajọ Stutern's Nigeria Graduate Report sọ pe ida ogoji awọn to n kẹkọ̣jade ni Naijiria ni kii ri iṣẹ.

Nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni Ọjọgbọn Bila ṣi ṣọọbu jorinmọrin rẹ niluu Zaria, ọdun 2022 lo gboye Ọjọgbọn.