'Fúnra wa la gba àwọn ọmọbìnrin wa ní àhámọ́ ajínigbé, kìí ṣe ọlọ́pàá'

Oríṣun àwòrán, Ebi Al-Kadriyah
Kìí ṣe ohun tuntun mọ́ pé àwọn ọmọbìnrin márùn-ún láti inú mọ̀lẹ́bí Al-Kadriyaj tí àwọn ajínigbé jí gbé ti gba ìtúsílẹ̀.
Ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ogúnjọ́, oṣù Kìíní, ni àwọn ọmọbìnrin náà gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé láti ọjọ́ kejì, oṣù Kìíní, tí wọ́n ti wà ní àhámọ́ wọn.
Ní ilé ìgbé àwọn ọmọbìnrin yìí tó wà ní Abuja ni àwọn ajínigbé náà ti jí àwọn ọmọbìnrin mẹ́fà àti bàbá wọn gbé.
Wọ́n tú bàbá àwọn ọmọbìnrin yìí, Mansour Al-Kadriyah sílẹ̀ pé kí ó lọ wá ọgọ́ta mílíọ̀nù náírà láti fi tú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ́ẹ̀fà sílẹ̀.
Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí bàbá náà kò rí owó yìí san ni àwọn ajínigbé pa ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin yìí, Nabeeha Al-Kadriyah tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ipele tó kẹ́yìn nílé ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti fi ṣèkìlọ̀ fún ẹbí Al-Kadriyah pé kí wọ́n tètè wá owó wá.
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé àwọn kò ní gba ọgọ́ta mílíọ̀nù Naira tí àwọn ti ṣáájú bèrè tẹ́lẹ̀ fún mọ́, pé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nùNaira ni àwọn fẹ́ gbà lórí ọmọ márùn-ún tó ṣẹ́kù ní àkàtà àwọn.
Èyí fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dá owó fún àwọn ẹbí náà láti gba àwọn ọmọbìnrin náà sílẹ̀.
Àbálọ àbábọ̀, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn ọmọ náà tó gba ìtúsílẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n lo ọjọ́ mọ́kàndínlógún ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.
Báwo ni àwọn ọmọ náà ṣe gba ìtúsílẹ̀?
Ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni agbenusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja, Josephine Adeh fi ìkéde síta pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti dóòlà àwọn ọmọbìnrin Al-Kadriyah kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.
Adeh nínú àtẹ̀jáde tó fi léde ní àpapọ̀ àwọn ẹ̀ka ọlọ́pàá tó ń gbógun ti ìjínigbé àtàwọn ọmọ ogun ni àwọn fi rí àwọn ọmọ náà tú sílẹ̀.
Àmọ́ nígbà tí BBC News Yoruba kàn sí ẹbí Al-Kadriyah lórí bí àwọn ọmọ náà ṣe gba ìtúsílẹ̀, ohun tí wọ́n sọ yàtọ̀ sí òun tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ.
Àbúrò bàbá àwọn ọmọbìnrin náà, Sheriff Al-Kadriyah, tó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀sìn àti ìtàn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Kwara (KWASU) ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ kò rí bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe ṣọ́.
Sheriff Al-Kadriyah ṣàlàyé pé àwọn san owó ìtúsílẹ̀ fún ajínigbé kí wọ́n tó tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀.
Ó ní lẹ́yìn bíi ọjọ́ mẹ́rin tí àwọn ti san owó ìtúsílẹ̀ ni àwọn ajínigbé ọ̀hún tó pe àwọn pé kí àwọn wá gba àwọn ọmọbìnrin náà ní ìpínlẹ̀ Niger.

"Àwa bíi ẹbí mẹ́ta ni a pàdé níbi tí a ti san owó ìtúsílẹ̀ láti gba àwọn ẹbí wá kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé yìí."
"Mi ò lè sọ pé iye báyìí la san fún àwọn ajínigbé láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ yìí nítorí ètò ààbò àmọ́ owó tó pọ̀ ni wọ́n gbà lọ́wọ́ wá."
Ó ní lóòótọ́ ni pé àwọn ọmọ ogun tẹ̀lé àwọn tó gbé owó lọ láti dáàbò bò wọ́n.
"Kò sí ohun tó jọ pé ọlọ́pàá ló gba àwọn ọmọ náà kalẹ̀ rárá, a san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé ni.
"Àwọn ajínigbé ló pè wá lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀, wọ́n pè wá, fún wa ní ibi tí a ti ma pàdé.
"Àwọn ọmọ ogun tẹ̀lé àwọn tó lọ kó àwọn ọmọ náà láti pèsè ààbò tó péye fún wọn, ọlọ́pàá kankan kò tẹ̀lé wá.
"A ò sọ pé ọlọ́pàá kò ṣiṣẹ́ o àmọ́ nípa ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọbìnrin Al-Kadriyah yìí, ọlọ́pàá kọ́ ló gbà wọ́n sílẹ̀, a san owó ìtúsílẹ̀ ni."
Sheriff Al-Kadriyah wá dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n dá owó fún wọn láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ náà, pé owó náà ló ran àwọn lọ́wọ́ láti fi rí àwọn ọmọ náà gbà kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Níbo ni àwọn ọmọbìnrin náà wà báyìí?

Ó tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà má fi dé láti àhámọ́ ajínigbé lẹ́yìn tí wọ́n lo ọjọ́ mọ́kàndínlógún, wọ́n nílò ètò ìlera tó péye.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ọmọ náà ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Ó fi kun pé bàbá àwọn ọmọ náà ṣì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí òun náà ti ń gba ìtọ́jú nítorí àwọn ajínigbé náà ṣe é léṣe gidi kí wọ́n tó tu sílẹ̀ láti lọ wá owó.
"Wọ́n lu bàbá àwọn ọmọ náà gan-an nítorí igba mílíọ̀nù ni wọ́n sọ pé kó kọ́kọ́ lọ mú wá nígbà tí wọ́n fi ma tu sílẹ̀ àmọ́ tó sọ fún wọn pé òun kò ní."
"Èyí ló mú kí wọn ó lù ú gidigidi, tí ó sì nílò àmójútó ètò ìlera tó sì ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ àti pé ara rẹ̀ ti ń balẹ̀."
"Ènìyàn mẹ́rin ni àwọn ajínigbé pa lọ́jọ́ tí wọ́n pa Nabeeha."
Sheriff Al-Kadriyah tún ṣàlàyé pé lọ́jọ́ tí àwọn ajínigbé ránṣẹ́ pé àwọn láti wá gbé òkú Nabeeha, àwọn òkú ènìyàn mẹ́ta míì wà níbẹ̀ tí wọ́n ti pa kalẹ̀ náà.
Ó wá rọ ìjọba láti mójútó ètò ààbò, kí òpin le débá ìjínigbé tó ń fi ojoojúmọ̀ wáyé ní Naijiria.















