Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì bò èèyàn bí i 47 mọ́lẹ̀ ní Yunnan, China

Aworan isẹlẹ ilẹ riri ni China

Oríṣun àwòrán, SUPPLIED

O to eeyan mẹtadinlaadọta to tiha sinu ilẹ lẹyin ti iṣẹlẹ ilẹ riri waye ni owurọ ọjọ Ajẹ ni guusu iwọ oorun orilẹede China, Yunnan.

Aarẹ Xi Jinping ti rọ araalu paata lati tu sita lati doola ẹmi awọn eeyan ti wọn ri mọlẹ eyi to yoo mu adikun ba iye ijamba ti yoo waye

O si rọ ki wọn se ni o ni kiakia. BBC ko le ti fi idi rẹ mulẹ boya ẹmi eeyan ti bọ nipasẹ isẹlẹ ilẹ riri naa.

Fọnran lati ọwọ ileeṣẹ oniroyin abẹle safihan bi awọn araalu se n gbiyanju lati doola ẹmi awọn eeyan to ri mọlẹ.

Isẹlẹ yii waye ni deede ago mẹfa ku isẹju mẹsan an , ti ileeṣẹ iroyin CCTV si jẹ ko di mimọ pe agboole mejidinlogun ni awọn eeyan to di awati ti wa.

Ọkan lara awọn eeyan to jẹ ọkunrin ni wọn ti dola gẹgẹ ileeṣẹ iroyin abẹle se salaye.

O le ni ẹẹdẹgbẹta eeyan ti ijọba ti gbe kuro ni agbegbe naa lẹyin ti isẹlẹ ilẹ ọhun.

Olugbe agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Jimu News pe isẹlẹ ilẹ riri naa waye lasiko ti ọpọ awọn eeyan n sun lọwọ.

“Ariwo naa pọ, ti gbogbo ilẹ si n mi. Isẹlẹ ilẹ riri nla ni.”

Awọn alasẹ ko ti sọ pato ohun to fa isẹlẹ ilẹ riri naa.

Ninu oṣu kinni ọdun 2013, o to eeyan mejidinlogun to padanu ẹmi wọn ni Zhenxiong, ni ilu Zhaotong lẹyin isẹlẹ ilẹ riri kan to waye.