Makinde sọ̀rọ̀ lórí ibi tí ǹnkan dé dúró nípa ìbúgbàmù tó wáyé ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, X/Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kan sara si ẹka eto ilera nipinlẹ Oyo fun bi wọn se ri i pe pupọ ninu awọn eeyan to farapa nibi isẹlẹ ibugbamu to waye ni agbegbe Bodija niluu Ibadan, ti kuro ni ile iwosan.
Ninu ikede to fi si oju opo ayelujara X rẹ, ni alẹ ọjọ Aiku, ni Gomina Makinde ti sọ pe ida aadọruun ninu awọn eeyan to farapa, lo ti kuro nileewosan bayii, nitori pe ara wọn ti ya.
“Ikọ eleto ilera ati kọmisana fun eto ilera nipinlẹ Oyo ṣe abẹwo si ile iwosan meji nibi ti awọn eeyan to farapa wa, ti ida aadọrun ninu awọn eeyan naa, lẹyin ti wọn gba itọju to peye, ti lọ si ile wọn.”
Gomina ni apapọ eeyan to jade laye nibi isẹlẹ ibugbamu naa ko tii kọja marun un, ti awọn ikọ eleto ilera si ti bẹrẹidanilẹkọọ, ati imulọkan le fun awọn eeyan to kagbako ninu ibugbamu naa.
Ileeṣẹ ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri niluu Ibadan, lo ni eto naa ti n waye, lati ri pe isẹlẹ ọhun ko ṣe ijamba fun ọpọlọ wọn.
Bakan ni gomina tun dupẹ lọwọ akẹẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Ẹkọ, Gomina Babajide Sanwoolu fun bi o ṣe pese iranlọwọ, nipasẹ ajọ pajawiri ipinlẹ Eko fun lilo fun ipinlẹ Oyo.
Gomina Seyi Makinde ni awọn agbofinro si n se iwadii lori ohun to fa ibugbamu ọhun.
Bakan naa lo se ileri pe esi iwadii naa yoo jẹ ohun ti gbogbo eeyan yoo mọ nipa rẹ, to ba jade sita.
O ni iṣejọba oun yoo ri pe o pese iranlọwọ fun gbogbo awọn eeyan to lugbadi isẹlẹ ibugbamu yii, "ti a o si ri i pe gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ jere isẹ ọwọ wọn.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















