Owó ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì IELTS táwọn tó bá fẹ́ jápa ń ṣe ti di N139,000 báyìí

Aworan awọn arinrinajo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ British Council to n ṣagbatẹru idanwo ede Gẹẹsi IELTS fawọn to ba fẹ rinrin ajo lati Naijiria lọ si orilẹede UK tabi Amẹrika ti ṣe afikun owo idanwo naa.

Ida mọkandinlọgbọn ninu ọgọrun ni afikun owo to gori owo idanwọ ọhun.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ naa fi lede loju opo igbọrọkaye rẹ, ẹnikẹni to ba ti fẹ ṣe idanwo yii yoo maa san ẹgbẹrun mọkandinlogoje naira(N139,000) lati ọjọ kini oṣu keji ọdun 2024 yii.

IELTS jẹ idanwo ti ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn kii ṣe ọmọbibi ilẹ Gẹẹsi maa n ṣe gẹgẹ ẹri pe wọn gbọ ede oyinbo daadaa.

Ajọ British Council ni afikun owo idanwo naa nii ṣe pẹlu eto ati ṣe agbekalẹ idanwo naa to ti di owo gọbọi bayii.

Ajọ naa ṣalaye lori itakun igbọrọkaye rẹ bayii pe ‘’a n fi asiko yii sọ fawọn eeyan pe afikun ti de ba owo idanwo IELTS.

Lati ọjọ kini oṣu Keji ọdun 2024 yii si ni awọn eeyan yoo bẹrẹ si ni maa san owo tuntun fun idanwo yii.

Eyi yoo fun wa lanfaani lati le ṣe iranwo fawọn to ba fẹ ṣe idanwo yii ki wọn le yege.’’

Ọrọ British Council

Oríṣun àwòrán, British Council

Ni nkan bii oṣu marun un sẹyin ni wọn ṣe afikun owo idanwo yii.

N80,000 ni wọn maa n ṣe idanwo yii tẹlẹ ki wọn to sọ ọ di N90,000.

Lati N90,000 ni wọn ti gbe e lọ si N107,500 loṣu Kẹsan an ọdun 2023.