Ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò níbí ilé alájà mẹ́wàá Mandilas tó jóná l’Eko

Aworan ile to n jona

Oríṣun àwòrán, Lagos State Fire and Rescue Service

Ọpọ dukia ṣofo lẹyin ti ina ṣadeedee ṣẹyọ nile alaja mẹwaa Mandilas niluu Eko.

Ni agbegbe Broad Street ni Lagos Island ni ile ọhun ti jona.

Ajọ ipinlẹ Eko to n ri si ọrọ ina pipa ati idoola ẹmi, Lagos State Fire and Rescue Service lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Ọgagba LSFR, Arabinrin Margaret Adeseye to fi atẹjade ọhun sita ṣalaye pe aja kini ni ina ọhun ti bẹrẹ.

Ọgagba ajọ LSFR ni ko si ẹni to le sọ ohun to ṣe okunfa naa bayii.

Arabinrin Margaret sọ pe ina naa ti ran de aja kẹrin bayii.

O fidi rẹ mulẹ pe awọn pana-pana ti wa nibẹ, wọn ṣi ti n gbiyanju lati pa ina ọhun.

Lẹyọ o rẹyin, awọn pana-pana pada ri ina ọhun pa, amọ, ọpọ nkan ni ina ti jo raurau.

Aworan ile to n jo

Oríṣun àwòrán, Lagos State Fire and Rescue Service

Aworan ile to n jona

Oríṣun àwòrán, Lagos State Fire and Rescue Service