Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣàfihàn àwọn ajínigbé àti àwọn afurasí 16 nílùú Abuja

Aworan awọn ajinigbe niluu Abuja

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria Police

Lẹyin idasilẹ Special Intervention Squad lati ọwọ Ọgagba ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, IGP Kayode Egbetokun, ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹrindinlogun pẹlu awọn ohun ija ti wọn fi sọsẹ niluu Abuja.

Lara awọn afurasi ti Ileeṣẹ ọlọpaa ṣafihan lọjọ Ṣatide ni awọn ajinigbe mẹta lati Bwari- Idris Ishaku, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Bala Umar, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Dahiru Salisu, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ti wọn fọwọsowọpọ lati ji awọn eeyan gbe, ti wọn si tun jale ni agbegbe ijọba ibilẹ Bwari ati awọn agbegbe mii niluu Abuja.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Muyiwa Adejobi buwọlu fun awọn akọroyin salaye bi ikọ ileeṣẹ ọlọpaa se mu awọn mẹtala yooku fun oniriru ẹsun ọdaran mii.

“Lara awọn aṣeyọri ọlọpaa ni bi wọn dena ijinigbe, ti ọwọ si tẹ awọn ajinigbe to n da agbegbe Bwari laamu, ti a ri awọn ibọn gba lọwọ wọn.”

Bẹẹ ba gbagbe, ariwo sọ nigba ti awọn ajinigbe ji Baba ati awọn ọmọ rẹ marun un gbe ni agbegbe Bwari lọjọ Kẹta oṣu kinni ọdun 2024.

Awọn ajinigbe naa sekupa ọkan lara awọn ọmọbinrin naa ti orukọ n jẹ Nabeehah lẹyin ti awọn obi wọn ko ri owo itusilẹ ti awọn ajinigbe naa bere fun, eyi to jẹ ọgọta milọnu naira.

Adejobi ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ si ni ma se ọfin toto awọn ajinigbe naa, ti ọwọ si ti tẹ awọn eeyan kan ti wọn mọ nipa isẹlẹ naa.

“Lẹyin ti iroyin nipa ijinigbe ọkunrin kan ninu ọkọ Hilux pẹlu nọmba idanimọ No. RBC 90 DL tẹ wa leti, eyi ti awọn ajinigbe mẹrin kan ti wọn wọ asọ funfun ninu ọkọ Mercedez Benz ji gbe,

"Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe awọn ajinigbe naa gbe ọkunrin lọ si ipinlẹ Kano nibi ti wọn ti fi tipatipa yọ owo toto ẹgbẹrun lọna ọọdẹgbẹta ninu apo owo rẹ .

“Sugbọn ilẹ mọn mọ awọn ajinigbe naa nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa kawọn mọ ile epo kan nipinlẹ Kaduna ti awọn mẹta ninu wọn si salọ.

‘’Ọkan lara awọn ti ọwọ tẹ ni orukọ n jẹ Chinaza Philip Okoye Micheal, ti iwadii si fihan pe saaju ni ọwọ ti Chinaza ati awọn akẹgbẹ rẹ ninu oṣu kọkanla ọdun 2023, ti wọn si foju ba ileẹjọ giga Kwali niluu Abuja fun ẹsun ijinigbe ,”

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ọ̀dọ́mọbìnrin mẹ́fà tí àwọn ajínigbé gbé nílùú Abuja

Awọn ọmọbìnrin naa

Oríṣun àwòrán, Ẹbi AL-KADRIYAR

Ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja, ti doola awọn eeyan kan to wa ni ahamọ ajinigbe.

Ninu ikede to fi sita lori ayelujara X, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Abuja, SP Josephine Adeh, sọ pe ni nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Abamẹta, ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni wọn doola wọn.

Ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni awọn ajinigbe naa gbe awọn ọdọmọbìnrin mẹfa naa, pẹlu baba wọn, ni agbegbe Zuma 1, ni ijọba ibilẹ Bwari.

Sugbọn wọn pada yọnda baba náà, Mansoor Al-Kadriyar, lati lọ ọ wa ọgọta miliọnu fun itusilẹ wọn.

Bakan naa ni wọn pa ọkan lara awọn ọmọbìnrin naa, Nabeeha, to wa ni ipele to kẹhin ninu ẹkọ rẹ ni fasiti, lọjọ Ẹti to kọja.

Eyi ni wọn lo jẹ ikilọ pe owo itusilẹ nla naa gbọdọ jẹ sisan.

Ijinigbe naa fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaa lori ayelujara, ti eyi si mu ki ọpọ o maa kọminu lori eto aabo ni Naijiria.

Bawo ni wọn ṣe doola wọn?

SP Adeh ṣalaye pe ajọṣepọ ẹka ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe, ati awọn ọmọ ogun, lo mu ki aṣeyọri naa waye.

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe ninu aginju Kajuru, nipinlẹ Kaduna state ni wọn ti doola awọn eeyan naa, wọn si ti wa ni ile pẹlu ẹbi won.

Sugbọn ko sọ boya won san owo itusilẹ ti awọn ajinigbe beere fun, tabi boya ọwọ tẹ ẹnikẹni ninu wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa rọ awọn olugbe ilu Abuja, lati maa pe awọn nọmba pajawiri yii, lati ṣe afisun awọn nnkan to mu ifura dani:

08032003913, 08061581938, 07057337653, ati 08028940883.

PCB: 09022222352.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2