Mo ṣèesì yìnbọn pa èèyàn méjì lásìkò ìdigunjalẹ̀ báńkì tó wáyé l'Offa, Afurasí jẹ́wọ́ níléẹjọ́

Banki niluu Offa

Oríṣun àwòrán, AYOBAMI AGBOOLA

Ọkan ninu awọn olujẹjọ to n jẹjọ ni ile ẹjọ gíga, ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara, lori ẹsun ipaniyan, idigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ iyẹn Ibikunle Ogunleye ti jẹwọ fun ile ẹjọ pe, esi loun fi fa oko ibọn ti o si yin pa araalu meji nibi idigunjale to sẹlẹ ni ilu Offa.

Ti ẹ o ba gbagbe, ni ọjọ karun osu kẹrin ọdun 2018 ni awọn adigunjale kan ya wọ ilu Offa ni ipinlẹ Kwara ti wọn si fọ awọn banki ilu naa, wọn si tun pa eeyan mẹtalelọgbọn.

Ogunleye ti o jẹ olujẹjọ keji lo fi eleyi to ile ẹjọ leti nibi igbẹjọ toni nigba ti agbẹjọro ìjọba, Rotimi Jacobs SAN n fọrọ wa lẹnu wo.

Ṣaaju ni olujẹjọ ọun ti sọ fun ile ẹjọ wi pe oun ki i ṣe ara awọn adigunjale naa, oun ko si tun wa ni ilu Offa lọjọ ti idigunjale ati ipaniyan naa sẹlẹ.

Ogunleye sọ pe oko loun wa ni ọjọ buruku esu gbomimu naa ti taya mọto oun si bajẹ nigba toun dari lọ sile.

O ni idojukọ yi lo mu oun rin irin ajo lọ silu Osogbo lati ra taya mii si moto oun.

Eyi lo mu ki agbẹjọro ijọba Rotimi Jacobs ni ki o ka ijẹwọ ti o se ti o si fi ọwọ ara rẹ kọ kalẹ sinu iwe fun awọn ọlọpaa nigba ti wọn mu un pe ko wa wi tẹnu rẹ.

Ninu iwe naa lo ti wa lakọọlẹ pe, olujẹjọ keji naa seesi fa oko ibọn, ibọn naa si yin pa eeyan meji nibi idigunjale ọun to mi gbogbo Naijiria titi.

Agbẹjọro Jacobs wa sọ fun ile ẹjọ pe ki agbẹjọro olujẹjọ ọun iyẹn Mathias Eberibe fi iwe iraja (receipt) taya naa ti onibara rẹ ra lelẹ fun Ile ẹjọ.

O ni ki o si tun fii sinu iwe nigba ti yoo ba fi lede fun ile ẹjọ.

Lẹyin eyi ni ile ẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ keji osu keji ọdun yi