Àwọn ẹbí Mandela fẹ́ ta aṣọ, Bíbélì, Kùránì àtàwọn dúkìá rẹ̀; ìjọba South Africa pè wọ́n lẹ́jọ́

Oloogbe Nelson Mandela

Ariyanjiyan kan ti n waye bayii laarin awọn ẹbi Oloogbe Nelson Mandela, ajijagbara ati aarẹ South Africa tẹlẹ, pẹlu ijọba orilẹ-ede naa.

Awọn nnkan eelo ti Mandela lo nigba aye rẹ tawọn ọmọ rẹ fẹẹ ta lowo nla bayii lo si fa a .

Awọn nnkan eelo bii ọpa ti Mandela fi rin, Bibeli, Kurani, kaadi idanimọ rẹ, aṣọ ṣẹẹti rẹ ti wọn kọ Madiba si, ohun elo to lo fun igbọran daadaa, awọn ẹbun to gba latọwọ awọn olori orilẹ-ede lagbaaye ati bẹẹ bẹe lọ, ni awọn ẹbi rẹ ti kede pe awọn fẹẹ ta lowo nla fẹni to ba le sanwo to pọ ju lori wọn.

Ọmọbinrin Mandela to dagba ju, Makaziwqe Mandela lo n ṣagbatẹru tita awọn nnkan naa l’Amẹrika, eyi to mu ijọba South Africa koro oju si tita yii.

South Africa ni awọn lawọn ni awọn ẹru naa bayii, ogun orilẹ-ede naa lapapọ ni, ki i ṣe ti Mandela mọ.

Ijọba South Afica sọ pe ọmọ Mandela ko lẹtọọ lati ko awọn nnkan naa kuro niluu awọn lọ s’Amẹrika.

‘A ti pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun lati dẹkun tita awọn dukia naa’

’O ṣe pataki pe ka tọju awọn nnkan ti Oloogbe Mandela duro fun nigba aye rẹ, ka si ri i daju pe orilẹ-ede yii ni wọn wa, kawọn irandiran to n bọ le de ba a.

Ọdun 2021 ni awọn ẹbi ti kọkọ fẹẹ ta awọn dukia yii, ijọba South Africa ni ko gba fun wọn.

2022 ti wọn tun gbe igbesẹ lati ta a, ijọba tun faake kọri. Ọdun naa ni wọn si gbe ẹjọ lọ si kootu.

Wọn ti kede awọn dukia naa sori atẹ lọdọ ileeṣẹ kan ni New York.

Fun apẹẹrẹ, $20,000 (£16,000) ni wọ lo ṣee ṣe ki ohun eelo igbọran daadaa naa to, aṣọ ṣẹẹti Mandela ko si le din ni $70,000.

Lasiko ta a pari iroyin yii, awọn ẹbi Mandela ko ti i wi nnkan nipa ẹjọ tijọba ilu wọn n ba wọn fa.

Asia South Africa

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ kan ti wọn n pe South African Heritage Resources Agency (Sahra), ṣalaye pe awọn ti gbe igbeṣẹ ti yoo dena tita awọn dukia naa, nipa pipe ẹjọ si kootu Ko-tẹ-mi-lọrun.

Bakan naa ni wọn sọ pe ileeṣẹ aṣa ati iṣẹ pẹlu eyi to n ri si ere idaraya ti darapọ mọ pipe ẹjọ naa.

Minista fun ere idaraya ni South Africa, Zizi Kodwa, ṣalaye pe awọn ko le laju silẹ ki ogun ini orilẹede awọn bọ si ibomiran.

Ero awọn araalu ṣọtọotọ

Ọrọ dukia Madiba yii ti da orile ede South Africa si meji.

Bawọn kan ṣe n sọ pe kijọba fi awọn ẹbi Mandela silẹ ki wọn ṣe ogun rẹ bo ba ṣe wu wọn, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe kijọba ma jẹ ki wọn ta a, wọn ni ti South Africa ni.