'Lẹ́yìn aṣọ tó wà lọ́rùn wa, kò sí ẹni tó rí píìnì mú jáde, gbogbo àwọn ìwé ẹ̀rí wa ló jóná deérú'

Kò sí ẹni tó rí abẹ́rẹ́ mú jáde yàtọ̀ sí aṣọ tó wà ní ọrùn oníkálukú, kódà gbogbo ìwé ẹ̀rí wa àti àwọn dọ́kúmẹ́ǹtì pàtàkì míì ló jóná deérú.
Pẹlu ibanujẹ ni awọn eniyan ti ijamba ina to waye ni agboole Maigida, ni agbegbe Ẹdun, Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara ni ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kiini ọdun 2024 fi n sọrọ lori awọn dukia ti wọn padanu ninu ijamba naa.
Ko din ni ọgọrun-un eeyan ti ijamba ina to jo yara ojule mẹrinlelogoji ọhun sọ di alainilelori mọ.
Nibi ijamba ina ọhun, awọn dukia olowo iyebiye to fi mọ dọkumenti pataki ati awọn iwe ẹri lọkan o jọkan lo jona raurau.
Gbogbo igbiyanju awọn araadugbo ati awọn oṣiṣẹ panapana lati pa ina naa ko to di nnkan nla lo ja si pabo, ṣe ni ina ọhun n fẹju bii ina inu ẹẹrun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Hassan Adekunle ni ilẹ ni ẹnikan ti wọn ko mọ n dana sun, ko to ran mọ ile to si ba ọpọ dukia jẹ.
Nigba ti BBC News Yoruba sabẹwo si agboole Maigida, ti iṣẹlẹ laabi naa ti waye lọjọ Iṣẹgun lati mọ ibi ti nnkan de duro, o jọniloju pe eefin ina ṣi n ru jade ni awọn yara kọọkan.
A tun ri awọn iya ile to joko sita ni isọri isọri tan n woye ọjọ, awọn mii n bomi loju nitori ko si ibi ti wọn yoo forika.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Bí ìjànmbá iná náà ṣe bẹ̀rẹ̀


BBC News Yoruba ba ọkan lara awọn ọmọ ile naa sọrọ iyẹn Alaba Maigida, o salaye pe ita loun wa nibi ti oun ti n taja.
O ni ojiji lawọn ri pe awọn obinrin sare jade, ti wọn n pariwo ina, gbogbo awọn sare wọle, wọn si doju omi kọ yara ti ina naa ti n jo lai mọ pe ina naa ti gba ori orule tan ka awọn yara yooku.
"Bi ina ṣe bẹrẹ ni yara kan lo n ran mọ gbogbo awọn yara to wa layiika, ko si pẹ rara to fi ran mọ gbogbo awọn yara to wa ni agboole naa ati Mọsalasi.
"Gbogbo igbiyanju wa lati pa a lo ja si pabo, gbogbo eeyan lo sa sita nigba ti ina ti gba gbogbo ile, sibẹ, awọn eeyan n pọn omi wọle lati ita lati pa ina ọhun.”
O ni ki awọn oṣiṣẹ panapana to de, nnkan ti bajẹ jina.
"Ko si ẹni to ri abẹrẹ mu jade yatọ si aṣọ to wa lọrun onikaluku, koda gbogbo iwe ẹri wa ati awọn dọkumenti pataki mii lo jona deeru.

"Awọn olugbe kan lọ sun ile molẹbi tabi ọrẹ wọn, awọn mii sun inu Mọsalasi.
"Gbogbo dukia ti a padanu n lọ bi ọgọrun milionu naira, tori yatọ si ile, dukia awa olugbe to ṣegbe sinu iṣẹlẹ naa ko ṣe e fẹnu sọ.
O fi kun pe, ohun to sokunfa ijamba naa ṣi ṣokunkun si awọn, tori ko si ina mọnamọna nigba ti o bẹrẹ, bẹẹ si ni kii ṣe pe awọn n sunlẹ ni ayika, Ọlọrun nikan loye ibi ti ina naa ti sẹyọ.
O dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe bi awọn ti ẹ padanu gbogbo ẹru ati ile awọn, ko si ẹmi ẹni ti o ba iṣẹlẹ naa lọ.
Gomina Ipinlẹ Kwara, Mallam AbdulRahman AbdulRazaq ati awọn asofin ile igbimo asofin ti ijọba apapọ ati ijọba ibilẹ naa ti sabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, lati mu awọn ti ọrọ kan lọkan le.















