Iná jó ọjà ńlá Fanteka ní Kaduna, ṣọ́ọ̀bù 250 jóná
Àkọlé àwòrán, Ina ṣẹyọ ni ọja Fanteka ni ipinlẹ Kaduna lẹkun ariwa Naijiria. Ko din ni ọtalelugba o din mẹwaa (250) ati ẹgbẹlẹgbẹ dukia to fi ara gba a.
Àkọlé àwòrán, Babalọja ọja naa, Alhaji Sulaiman Shehu ṣalaye fun BBC pe alẹ Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye ti o si kan awọn ṣọbu ti wọn fi pako kọ ni ọja Fantẹka naa.
Àkọlé àwòrán, Babalọja ọja Fanteka tun ṣalaye pe titi di bayii, àwọn ko tii le sọ ni pato ohun gan to ṣokunfa ina naa.
Àkọlé àwòrán, Amọṣa, o ni awọn ọdẹ to n ṣọ ọja naa sọ pe awọn kẹfin ina naa loru ni agbegbe kan ninu ọja naa lẹyin ti ina mọnamọna de.
Àkọlé àwòrán, Olori ọja naa tun ṣalaye pe awọn sa ipa titi lati pa ina naa lasiko ṣugbọn pato ni ilakaka wọn ja si.
Àkọlé àwòrán, O fi kun un pe lootọ ileeṣẹ panapana wa nitosi ọja naa ṣugbọn “wọn ko ni ohun elo to to” lati pa ina naa.
Àkọlé àwòrán, Ninu ọrọ to sọ fun BBC, “A ni lati pe ileeṣẹ panapana apapọ to wa pada pa ina naa lẹyin o rẹyin ni.”
Àkọlé àwòrán, Babalọja ọja Fanteka ni wọn ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe odinwọn awọn ṣọọbu to bajẹ ati iye ọja ati dukia to ba ijamba ina naa lọ.
Àkọlé àwòrán, Bakan naa lo tun ke si ijọba lati ran awọn eeyan ti o fara kaasa ijamba naa nitori lọwọ yii ipa ti pin funwọn.
Àkọlé àwòrán, Ni Naijiria, ọdọọdun ni ijamba ina maa n waye kaakiri awọn ọja, eyi si maa n fa ofo ọpọlọpọ dukia.
Àkọlé àwòrán, Amọṣa, awọn ontaja ti ijamba ina naa kan maa n ri iranwọ lawọn ọna kan tabi omiran, bẹẹni awọn miran kii ri. Nṣe ni ijamba ina bẹẹ maa n sọ wọn di ẹdun arinlẹ nigba mii.
Àkọlé àwòrán, Amọṣa awọn onwoye n tọka si awọn ipenija sunkẹrẹ fakẹrẹ lawọn ọja gẹgẹ bi ohun kan to maa n fa idiwọ fun awọn ọkọ panapana to ba nsare ati pa ina lawọn ọja bẹẹ.
Àkọlé àwòrán, Aworan ijamba ina lọja Fateka ni ipinlẹ Kaduna