Wo iye ilé, ọọ̀físì àti àdúgbò tì ìbúgbàmù Ibadan kàn

Oríṣun àwòrán, bbc
- Author, Adesola Ikulajolu àti Olumide Owaduge
- Role, Akọroyin BBC
Alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii ni ibugbamu nla kan mi ilu Ibadan titi.
Ọpọ ile lo dawo ninu ibugbamu naa, ọpọ ọkọ bajẹ, eeyan mẹtadinlọgọrin farapa nigba ti eeyan mẹta jade laye.
Gomina Seyi Makinde ti sọ pe ado oloro ti awọn kan to n wakusa lọna aitọ lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Lara awọn agbegbe ti ibugbamu naa pa lara ree
Yatọ si awọn ile to parẹ atawọn to pa lara, awọn ile mii ati ọọfisi naa tun faragba ninu iṣẹlẹ ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn jina si adugbo Adeyi, ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Lara awọn ibi ti ibugbamu ọhun ti ba dukia jẹ ni Ile iwosan ijọba apapọ, UCH to wa niluu Ibadan.

Oríṣun àwòrán, James Igbasan
UCH

Oríṣun àwòrán, bbc
Nnkan bii kilomita mẹrin le diẹ lo wa laarin UCH ati adugbo Adeyi, sibẹ nnkan bii ile mẹrindinlogun ni ibugbamu naa pa lara nibẹ.
Akọrọyin BBC Yoruba to yọju si UCH jabọ pe ọpọ orule ati ferese awọn ọọfisi lo bajẹ ni UCH, sibẹsibẹ, ọpọ awọn to farapa nibi ibugbamu ọhun ni wọn ṣi lọ gba itọju nibẹ.
Ọga agba UCH, Jesse Abiodun Otegbayo sọ fun BBC pe eeyan mẹtala ni awọn adoola ẹmi gbe digbadigba wa si ọdọ awọn lẹyin iṣẹlẹ naa.
Akọroyin BBC foju ri ile, to fi mọ awọn ọọfisi mẹrindinlogun, to faragba ninu iṣẹlẹ naa.
Ile ogoji

Oríṣun àwòrán, bbc
Ayẹwo awọn ile to ni ipalara ninu ibugbamu ọhun le ni ogoji nigba ti awọn agbo ile bii ogun naa tun ni imọlara rẹ.
Lara awọn ile naa ni orule wọn fo yọ ti awọn gilaasi ferese awọn ile mii si fọ si wẹwẹ.
Ayẹwo lati oju ofurufu fi han pe iṣẹlẹ naa milẹ de adugbo Aderinola ati Canon Odusanwo, bẹẹ naa lo tun de Apete, eyii to jẹ nnkan bii kilomita mẹsan an si adugbo ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ijọba ipinlẹ Oyo ti ni ki awọn olugbe Adeyi ti ibugbamu naa ti waye maa ti lọ si ile wọn lasiko yii lẹyin ti ijọba ṣeto ibi ti wọn yoo ṣi maa gbe fun wọn fun igab diẹ.
Ẹwẹ, minisita fun idagbasoke ohun alumọni, Dele Alake ti ke si awọn oṣiṣẹ rẹ lati bẹrẹ iṣẹ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.














