Àwọn adigunjalè ṣèkọlù sí oní POS ní Kwara, wọ́n tún pa obìnrin kan

Isọ POS ti awọn adigunjale naa ṣe ikọlu si ati aworan adigunjale

Ṣe ni igboro ilu Oke-Ọdẹ ni ijoba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara da paroparo afi bii ẹni pe gbogbo awọn to wa ninu ilu naa ti ko kuro.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọgara ọlọsa ṣe ṣọsẹ loju ọja ilu naa lọjọ Iṣẹgun nibi ti arabinrin olounjẹ kan, ẹni ọdun mejileladọta (52) ti wọn n pe ni Esther Tinuade Omotunde ti padanu ẹmi rẹ.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Igboro ilu Oke Ode da paro nitori awọn adigunjale to ṣekọlu sibẹ
Isọ oni POS ti awọn adigunjale naa ṣekọlu si

Nigba ti BBC News Yoruba ṣabẹwo si ilu Oke-Ọdẹ lori iṣẹlẹ laabi ọhun, awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ni nnkan bi ago mẹfa abọ ọjọ Iṣẹgun ni awọn adigunjale ya wọ ilu Oke-Ọdẹ ti wọn si n rọjo ibọn.

Igbagbọ wọn ni pe awọn adigunjale naa mọọmọ dabọn bolẹ lati fi dẹruba awọn eeyan lati ma sun mọ wọn.

Wọn ni sọọbu POS ọkunrin kan iyẹn Ọgbẹni Qudus ti o ni Al-Qudus Telecommunication ni awọn adigunjale naa dojukọ.

Wọn fi kun un pe awọn adigunjale naa to mẹrin niye wọn si gbe alupupu lati fi ṣẹsẹrin.

Ọjọ naa jẹ ọjọ ọja, oniṣowo POS yii si ni iwadi fihan pe o maa n lowo ni sọọbu ni gbogbo ọjọ ọja nitori awọn ọlọja to maa n san ati gba owo lọdọ rẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, bi wọn ṣe n yinbọn kaakiri ni ọta ibọn lọ ba Tinuade ni sọọbu rẹ nibi ti o ti n ta ounjẹ, o si ku loju ẹsẹ.

“Awọn adigunjale naa gbe owo ti a ko mọ iye rẹ ati awọn ẹrọ ibanisọrọ ti oniṣowo POS naa fi n ṣiṣẹ rẹ, bi wọn ṣe n lọ, ni ọta ibọn ọkan tan lara wọn, awọn ọdọ ilu si boo, wan luu, wọn si danu sun-un gudugudu nigba ti awọn mẹta yooku ribi salọ.”

Irú èèyàn wo ni olóògbé Tinuade?

Awọn ẹbi oloogbe n ṣedaro eniyan wọn
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwadii ikọ BBC ninu ilu naa fihan pe Tinuade jẹ onisowo worobo (provisions) ko to fi iṣẹ naa kalẹ nigba ti o jẹ gbese kan, to si lọ si ilu Eko lati lọ ṣiṣẹ.

Ko tii ju bi oṣu meji lọ to pada de si ilu Oke-Ode, o san gbese rẹ, o si bẹrẹ owo ounjẹ tita ko to wa di pe iṣẹlẹ naa ge ẹmi rẹ kuru.

Gbogbo awọn molẹbi lo wa ninu ibanujẹ ati iporuru ọkan lori ẹni wọn to lọ nigba BBC News tun sabẹwo si ile Aleye ti o jẹ agbole oloogbe Tinuade.

Akoko naa jẹ igba ti wọn ṣẹṣẹ ti itẹ de nibi ti wọn ti lọ sin oloogbe naa.

Aburo oloogbe, ti orukọ rẹ n jẹ Dorcas Adenike Olubiyọ sọ pe sọọbu oun ati ti ẹgbọn oun fẹgbẹkẹgbẹ, awọn si n ri ara awọn sugbon bi awọn adigunjale naa ṣe de ti wọn n yinbọn lọrọ ti di ẹni ori yọ o dile.

O ni igba ti wọn lọ tan tawọn de ṣọọbu rẹ lawọn ba ninu agbara ẹjẹ. ibọn gba apa wọle, o si gba aya rẹ jade.

O fi kun un pe ọdun yii ni ẹgbọn ohun ko ba pe ọmọ ọdun 52 ṣugbọn iku ja gba mọ awọn lọwọ.

Olori ẹbi ile Alẹyẹ, Hon. Tajudeen Alẹyẹ ninu ọrọ rẹ rọ ìjọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ lati ran awọn lọwọ lori eto aabo ni ilu naa.

O sọ wi pe awọn ajoji ti pọ ju ni ilu wọn ki ìjọba ba awọn wa nnkan ṣe si.

“Awa Yoruba o le dako mọ nitori awọn bororo maa fi maalu jẹ oko wa run, wọn o si da ti wọn si, a o si le sọrọ tori awọn loni ohun ija lọwọ.

“A rọ ìjọba kan dakun, kan bawa da si.”

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Agbenusọ ọlọpaa Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, sọ fun BBC pe igba ti awọn adigunjale naa n sa lọ ni awọn ọlọpaa ati awọn fijilante koju wọn, wọn si mu ọkan balẹ ninu wọn.