Wo àwọn àǹfàní ìlera tó wà lára ilá jíjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty
Ọkan pataki ninu irugbin ni ila jẹ ninu awọn nnkan ọgbin lapa Iwọ-Oorun kaakiri agbaye. Yatọ si pe o daa lati se lọbẹ, o tun ni awọn anfaani ilera to pọ gidi.
Loootọ lo jẹ pe ounjẹ ilẹ Adulawọ ni ila,ṣugbọn o fẹrẹ ma sibi ti wọn ko ti ki i gbin ila lagbaye.
India lo n gbin ila ju bi akọsilẹ ṣe wi, wọn n gbin (6,126,000 tonnes) lọdun.
Naijiria lo tẹle e ati Sudan.
Apejuwe ilá?

Oríṣun àwòrán, Getty
Ila jẹ eso kan ti a n lo bii ewebẹ, paapaa nilẹ Adulawọ.
Oriṣiiriṣii ila lo wa, eyi ni i ṣe pẹlu apa ibi ti wọn ti gbin ila naa lagbaaye.
Titobi ila, ewe rẹ, eso ati bo ṣe ri maa n yatọ sira wọn.
Akoko ti ila fi n so yatọ sira wọn pẹlu, oloṣu mẹta wa, ti yoo ti ṣee ka, bẹẹ si ni oloṣu mẹfa ati mẹsan-an wa pẹlu ki wọn too ṣee jẹ.
Àwọ̀ ila naa maa n yatọ sira wọn, awọn mi-in le jẹ alawọ ewe, ki omiran si ni awọ pupa.
Bi ila ṣe gún si naa aa maa yatọ sira wọn. Eso to wa ninu wọn naa yatọ pẹlu.
Anfaani to wa lara ila jijẹ

Oríṣun àwòrán, Getty
‘’Ila kun fun eroja ‘Vitamin’ ati ohun toyinbo n pe ni ‘Minerals’
Awọn bii vitamin B2, B3, B6, B9, ati Vitamin C. Ila kun fun Vitamin K pẹlu"
Onimọ nipa ounjẹ, Mamadou Seydou Bah, lo ṣalaye yii.
O ṣalaye pe awọn eroja to n gbogun ti kokoro ninu ara eeyan pọ ninu ila.
Kinni kan ta a mọ si ‘Antioxidants’, eyi to le dena arun jẹjẹrẹ, aisan ọkan atawọn mi-in wa ninu ila bi Onimọ nipa ounjẹ, Bah ṣe sọ.
Ilá jíjẹ ń ró awọn eroja ara to n dena aisan lagbara. Ki i jẹ ki eeyan tete gbo.
Marion Ezzedine lati Cote d’Ivore lo ṣalaye eyi.
Bi eeyan ba fẹ din ara sisan ku, ila daa lati maa jẹ, nitori ọra to wa ninu rẹ ko pọ.
Ila jijẹ n jẹ ki ounjẹ tete da ni inu, nitori eroja ‘fiber’ to wa ninu rẹ.
Eeyan le jẹ ila ni tutu, tabi ni gbigbẹ
" Ounjẹ kan to n jẹ ki igbọnsẹ ṣiṣe dirọrun ni, o si n ṣatunṣe odiwọn ọra ninu ẹjẹ eeyan." Bẹẹ ni Ezzedine wi.
Awọn anfaani mi-in ninu ila ree
Ila n ṣiṣẹ fun egungun lile ati ọkan to duro deede.
Oogun ni ila. O ṣee dena awọn aisan nla aṣekupani bii Jẹjẹrẹ, Itọ ṣuga ati Ẹjẹ riru gẹgẹ bi iwadii awọn onimọ nipa ounjẹ yii ṣe fidi ẹ mulẹ.
Bi o ṣe le ri awọn anfaani ila jẹ
Ọlọkan-o-jọkan ounjẹ la n bu ila le lori ta a si n jẹ,ṣugbọn yatọ si jijẹ lọbẹ, a le bọ ọ lasan ka si maa jẹ ẹ.
Eeyan le fi ila sinuu salaadi ko si jẹ ẹ ni tutu bẹẹ,ara ewe ni. Eeyan si le se e lọbẹ pẹlu.
‘’Ti a ba se ila ka too jẹ, o maa n tete da ninu ju teeyan ba jẹ ẹ ni tutu lọ’’ Dokita Ezzedine lo wi bẹẹ.
O ni sugbọn awọn eroja inu rẹ lalope to ba ṣi wa ni tutu ju nigba ti wọn ba se e lọ.
Paapaa julọ, Vitamic C inu rẹ ti ko fẹ ooru.
Ma ṣe jẹ ki ila rẹ pẹ ju lori ina
Onimọ ounjẹ Mamadou Seydou Bah, gba awọn eeyan nimọran lati ma ṣe jẹ ki ila wọn pẹ ju lori ina ti wọn ba n se e, ko ma baa pa eroja Vitmin C to wa nibẹ.
O ni ki wọn ma ṣe jẹ ko maa pẹ ju ninu oorun pẹlu bi wọn ba n sa a, nitori eyi le din agbara anfaani rẹ ku.

Oríṣun àwòrán, Getty














