Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dènà ìjàmbá iná lásìkò yí

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Kìí ṣe ohun tuntun pé ìjàmbá iná máa ń wọ́pọ̀ lásìkò ẹ̀rùn bí èyí tí a wà nínú rẹ̀ yìí.
Àwọn ìjàmbá iná yìí sì máa ṣokùnfà pípàdánù ọ̀pọ̀ dúkìá, tí àwọn mìíràn ti ẹ̀ máa ń mú ẹ̀mí lọ.
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá iná ló wáyé ní ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara láàárín oṣù Kọkànlá, tí ọyẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ títí di àsìkò.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kìíní ọdún 2024 ni ìjàmbá iná tó ṣọṣẹ́ ní ilé Maigida lágbègbè Edun, Ilorin sọ ènìyàn ọgọ́fà di aláìnílé lórí mọ́ nígbà tí iná náà ṣàkóbá fún ojúlé mẹ́rìnlélógójì.
Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn onímọ̀ nípa iná, iná jẹ́ ohun kòṣémàní tí ènìyàn nílò láti fi gbé ìgbé ayé tó ní ìtumọ̀.
Wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀rẹ́ ènìyàn ni iná tí èèyàn bá lò ó bí ó ṣe yẹ nítorí ènìyàn kò lè gbáyégbádùn láì sí iná àmọ́ tó lè di ọ̀tá ènìyàn tí a bá ṣì í lò.
Alukoro iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara, Hassan Adekunle ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ márùn-ún tí èèyàn le gbà láti fi dá ààbò bo ara rẹ àti ilé rẹ̀ lọ́wọ́ ìjàmbá.
Adekunle tó ṣàlàyé àwọn nǹkan tí èèyàn le ṣe nígbà tí ìjàmbá iná bá bẹ́ sílẹ̀ ni agbègbè tàbí ilé tí èèyàn bá wà.
Pípa àwọn ohun tó ń lo iná mọ̀nàmọ́ná kí o tó jáde kúrò nílé
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń gbàgbé láti pa iná mọ̀nàmọ́ná inú ilé tàbí ibi iṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń jáde.
Adekunle ní ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 2022 àti 2023 ló wáyé látara iná mọ̀nàmọ́ná.
Ó ní ó pọn dandan fún àwọn ènìyàn láti ri dájú pé wọ́n mú pípa àwọn nǹkan tó bá ń lo iná mọ̀nàmọ́ná bíi fáànù, fíríjì, amúlétutù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n bá ń jáde ní òkúnkúndùn.
Kí a ri dájú pé a ò jìnà sí ilé ìdáná lásìkò tí a bá ń dáná

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Bí ẹlòmíràn bá ṣe ń se oúnjẹ ni yóò máa fọ aṣọ, tọ́jú ọmọ, pọn omi, lọ ra nǹkan lóde, ẹlòmíràn ti ẹ̀ lè gbàgbé ara rẹ̀ sídì fíìmù lásìkò tó ń dáná lọ́wọ́.
Lóòótọ́, kìí ṣe wí pé kò da kí èèyàn máa ṣe iṣẹ́ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ papọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n kò dára kí ènìyàn jìnà sí ilé ìdáná lásìkò tó bá ń dáná lọ́wọ́.
Oúnjẹ le ru pa iná tí ènìyàn fi ń dáná tàbí kí nǹkan míì tó lè fa ìjàmbá iná le ṣẹlẹ̀, tí èèyàn bá wà ní ìtòsí lè jẹ́ kí a tètè dènà rẹ̀.
Mímú fóònù wọ ilé ìdáná jẹ́ ohun tí kò dára tó sì lè fa ìjàmbá iná pàápàá tí o bá ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì láti fi dáná.
Bẹ́ẹ̀ náà ni kò dára láti máa mi agolo gáàsì wò nítorí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè fa ìbúgbàmù, èyí tò lè fa ìjàmbá iná.
Dènà sísun ilẹ̀ ní agbègbè rẹ
Dídáná sun ilẹ̀ jẹ́ ohun tó lè ṣokùnfà ìjàmbá iná tí ènìyàn kò bá ṣọ́ra
Yàtọ̀ sí pé ó lè fa ìjàmbá iná, sísun ilẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́ máa ń fa àwọn kẹ́míkà tí kò dára sí àgọ́ ara tí èèyàn bá fa èéfín rẹ̀ símú.
Adekunle ní tó bá ṣe kọkọ fún èèyàn sun ilẹ̀, kí a ri dájú pé ibi tí a ti fẹ́ sun ilẹ̀ náà jìnà sí ilé dáradára, kí a sì dúró tì í títí tí ilẹ̀ náà máa fi jó tán.
Ó ní tí èèyàn bá ti ri dájú pé iná náà ti jó tán, kí èèyàn bu omi pa eérú rẹ̀ láti ri dájú pé kò sí iná tó lè rú jáde níbẹ̀ mọ́.

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Ṣọ́ra fún lílo káńdù láti máa fi tọná nínú ilé
Ìdásílẹ̀ àwọn lámpù tó ń gba iná mọ̀nàmọ́ná sára ti mú ìgbé ayé rọrùn sí dípò lílo káńdù.
Gbígbé káńdù sórí tábìlì àtàwọn nǹkan tó lè múná ti rán ẹ̀mí lọ sọ́run àìrò tẹ́lẹ̀.
Káńdù lè jábọ́ lórí ibi tí ènìyàn bá gbe sí tó sì lè fa ìjàmbá iná tó lágbára.
Adekunle wa rọ àwọn ènìyàn láti yé fi lámpù sínú iná mọ̀nàmọ́ná kalẹ̀ tí wọn k]o bá sí nílè pé kọ fi gbaná sára.
Ó ní tí iná mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n bá mú de bá lágbára ju lámpù náà lọ, ó lè fa ìjàmbá iná nígbà tí ènìyàn kò bá sí nílé.
Níní ohun tí wọ́n fi ń paná nínú ilé

Àwọn ohun èlò bíi fire extinguisher, aláàmù tí ènìyàn le tẹ̀ tí ìjàmbá iná bá bẹ̀rẹ wúlò láti fi dá ààbò bo ènìyàn lọ́wọ́ ìjàmbá iná.
Wọ́n ṣe é lò fún ẹni tí kìí ṣe òṣìṣẹ́ panápaná fún ààbò lásìkò tí ìjàmbá iná bá ṣẹlẹ̀.
Adekunle ní gbogbo ilé ló yẹ kó ní àwọn ohun èlò yìí fún ààbò tó péye.
Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti máa ri dájú pé wọ́n fi àbáwọlé ó kéré tán méjì sí ilé wọn nítorí à tì lè tètè rí bi jáde nígbà tí ìjàmbá bá ṣẹlẹ̀.
Kí ni ó yẹ kí ènìyàn ṣe tí ìjàmbá iná bá wáyé?

Ìjàmbá iná kìí ṣe ohun tí èèyàn máa ń múra sílẹ̀ fún àmọ́ ó ṣeéṣe kọ wáyé lásìkò tí èèyàn kò ní rokàn.
Adekunle ka àwọn nǹkan tí èèyàn lè ṣe tí ìjàmbá iná bá wáyé láti má fi jẹ́ kí ó pa ẹ́ lára nìyí:
- Fi ara balẹ̀, má jẹ̀ẹ́ kí ìpayà mú ọ ju bí ó ti yẹ lọ kí o lè ronú ohun tó yẹ kí o ṣe.
- Pe àkíyèsí àwọn ènìyàn tó wà ní àyíká rẹ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ kí wọ́n le kúrò ní ibi tí ewu wà.
- Pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná láti wá mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
- Bẹ̀rẹ̀ ìgbìyànjú láti pa iná náà gẹ́gẹ́ bí agbára bá ṣe mọ kí àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tó dé láì fi ẹ̀mí ara rẹ wéwu.
- Wá ọ̀nà láti jáde tí iná náà bá ti ń kọjá agbára nípa dídọ̀bálẹ̀ láti dènà kí èéfí má ba kò sí ẹ nímú.















