Èèyàn mẹ́ta jóná, ọ̀pọ̀ farapa níbí ìjàmbá tírélà mẹ́ta tó gbiná ní Ilorin

Ko din ni eniyan mẹta to padanu ẹmi ninu ijamba ọkọ kan to waye ni agbegbe Modi, Oko-Olowo lopopona Marosẹ Ilorin si Jebba.
Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kiini ọdun 2024 ni ijamba ọkọ ọhun, eyi to waye laaarin ọkọ tirela nla to gbe epo, ọkọ to ko ọti ati eyi to ko ẹwa soya ni wọn kọlu ara wọn.
Ni nnkan bi aago mẹta ọsan ku iṣẹju mẹrinla ni iṣẹlẹ laabi naa waye.
Ijamba ina naa ṣokunfa bi ọpọ eniyan ṣe jona ku kọja didamo, bẹẹ si ni ọpọ farapa yannayanna.
Abẹwo BBC News Yoruba si ibi ti ijamba ina ti waye fi han pe tirela to gbe epo bẹntiroolu naa ni taya rẹ fọ lori ere to si lọ kọlu tirela to ko ẹwa soya ti awọn mejeeji si gbina.


Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni tirela to ko kireti ọti ni tirẹ lasiko to n gbiyanju lati sa fun ijamba naa ni o jasi koto, to si gbina pọ.
Awọn eniyan naa ṣalaye pe bawọn igo ọti ṣe n sọ kẹu kẹu to n ta kaakiri ayika naa ni ina naa lo n gbilẹ sii.
Wọn ṣalaye pe eeyan marun-un ni wọn ti ri fa jade ninu ijamba naa, ti awọn mẹta ninu wọn si padanu ẹmi wọn loju ẹsẹ, ti awọn yooku si n gba itọju nile iwosan.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe awọn ni igbagbọ pe awọn eniyan kan ṣi wa labẹ tirela ti wọn o ri yọ jade.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, eeyan mẹrin ni wọn ti n gba itọju nileewosan bayii.
Alukoro ajọ FRSC nipinlẹ Kwara, Ọlayinka Basambo, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Hassan Adekunle ninu atẹjade kan to fi sita ni eniyan mẹta lo padanu ẹmi wọn ti awọn mẹjọ miiran si farapa ninu ijamba ọhun.
O ṣalaye pe gbogbo awọn to farapa ninu ijamba naa ni wọn ti n gba itọju nile iwosan.















