Alfa Okutagidi wọ́gilé ẹjọ́ tó pe Tani Olohun, ilé ẹjọ́ ní kó máa lọ láyọ̀ àti àláfíà

Oríṣun àwòrán, bbc
Idunu ṣubu layọ fun Tani Olohun atawọn ololufẹ rẹ lẹyin ti ile ẹjọ Upper Area to kalẹ si ilu Ilọrin wọgile ẹjọ ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.
Eyi waye latari igbesẹ tí olupẹjọ, iyẹn Alfa Okutagidi gbe nipasẹ awọn agbẹjọro rẹ pe ohun ti fọwọ wọnu, oun ko si ṣe ẹjọ mọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kọkandinlogun, osu Kejila, ọdun 2023 nibi ipade alafia to waye laarin Tani Olohun ati awọn Alfa Ilọrin ni ija ti pari ti alafia si ti jọba.
Pẹlu eleyii, awọn eniyan ti n tẹti leko lati mọ ohun ti ipade alafia naa yoo bi ni ile ẹjọ, ṣugbon ohun to sẹlẹ bayii fi han gbangba pe, alaafia ti jọba ni tootọ.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹjọ́
Awọn agbẹjọro Alfa Okutagidi ti olori wọn jẹ Usman Imam lo fi to ile ẹjọ leti pe awọn ko sẹjọ mo.
Wọn ni ipinnu yi ṣe pataki nitori olujẹjọ naa ti pegede lori awọn gbedeke ti awọn gbe kalẹ.
Ademola Banks to n duro fun Tani Olohun naa fẹnu si wi pe ipade alafia ti waye, ohun gbogbo si ti yanju laarin olupẹjọ ati olujẹjọ.
Adajọ Sunday Adeniyi gba si awọn agbẹjọro naa lẹnu, o ni ki Tani Olohun maa lọ layọ ati alafia.
Nigba ti Ademola Banks ba BBC Yoruba sọrọ, o wi pe alaafia ti jọba, irẹpọ to sọnu laarin ẹṣin ibilẹ ati Musulumi si ti pada.
O wa fọwọ sọya pe gbogbo ẹjọ to ku niwaju onibara ohun naa lo ma ni iyanju gẹgẹ bii eleyi ti ri.
Wayi o, o ṣi ku ẹjọ mẹta ninu mẹrin bayi fun Tani Olohun lati gba ominira patapata.
Gbogbo ẹjọ mẹtẹta yoku yii si ni yoo waye ni ọgbọn ọjọ, oṣu yi ni ile ẹjọ Majisireeti meji ọtọọtọ.
Ọkan niwaju, adajọ Mohammed Ibrahim ati ekeji, niwaju adajọ Mohammed Adam.














