'Mi ò rí nǹkan tó burú nínú bí èmi àti ọkọ mi ṣe jẹ́ àyàn'

Ayan to moju ilu daradara ni tọkọtaya Ogunniyi Ayọdele Stephen. Bakan naa ni wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ ilu titunṣe ni ilu Oro ni ipinlẹ Kwara.
Ọgbẹni Ogunniyi ṣalaye ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba pe kọlọkọlọ ti ọka n gba de inu ọka ni oun gba di ẹni ti o n tu ilu ṣe nitori pe kii ṣe iṣẹ ti oun kọ tabi yan laayo lati ipilẹ aye oun.
Amọṣa, ile ayan ni wọn ti bi iyawo rẹ, Oluwakẹmisọla bi o tilẹ jẹ wi pe ko fi bẹ mọ ohunkohun nipa ilu lilu tabi titunṣe ki o to pade ọgbẹni Ogunniyi.
Ifẹ to ni si ọkọ rẹ lo mu ki ọkan oun pẹlu fa si ilu lilu ati ṣiṣe.
Pásítọ̀ ni mo pe ọkọ̀ mi, mi ò mọ̀ pé onílù ni bii temi ni
Arabinrin Oluwakẹmi ṣalaye pe kii ṣe tori pe ọkọ oun jẹ onilu ti oun pẹlu si wa lati idile onilu loun fi fẹẹ.
O ni oun gan ko tilẹ tete mọ pe iṣẹ ilu ni ọkọ oun yan laayo nitori pe iṣẹ Pasitọ loun ro pe o n ṣe nigba ti ere aniyan ifẹ wọn bẹrẹ.
O ṣalaye siwaju sii pe ọpọ igba lawọn eeyan maa n ba awọn da apara pe, tọkọtiyawo onilu ti awọn si maa n fi ọrọ naa ṣe ẹrin rin.





