Wọ́n tà mí sínú ìgbéyàwó fún $9 nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méjìlá

Àkọlé fídíò, Wọ́n tà mí sínú ìgbéyàwó fún $9 nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méjìlá

Lagbaye, o to milọnu mejila ọdọmọbinrin ti wọn ko ti pe ẹni ọdun mejidinlogun ni ojo ori ti wọn n loyun lọdọdun.

Ọkan lara wọn ni Tamara jẹ.

Nigba to wa ni ọmọ ọdun ni awọn obi rẹ fi lọkọ, ti wọn si dọla mẹsan,.

Tamara sọ fun BBC pe ko wu oun lati ni ọkọ lasiko naa sugbọn awọn obi rẹ kọ jalẹ.

Bakan naa ni o tun loyun ni ọmọ ọdun mejila.

“Mo gbọ pe okunrin kan wa bẹbẹ lati fẹ mi,

“O si ti sanwo ori mi. Nigba na, ẹbi mi si ti lo owo ori mi.

“Wọn ni mo gbọdọ ṣe igbeyawo ṣugbọn mo kọ.

“Wọn tẹnu mọ, wọn si mu mi gba lati ṣe igbeyawo.”

Ọrọ pọ lẹnu Tamara. ẹ wo fọnran lati mọ ogun to waye si ọdọmọbinrin naa.

Aworan Tamara