Wo ìtàn ẹ̀bi Fela Anikulapo Kuti àti ẹ̀kọ́ tó yẹ kí o kọ́ nípa àwọn ọmọ tó dàgbà níbẹ̀

Àkọlé fídíò, Ta ni Fela Anikulapo Kuti, Jesse Ransome Kuti, Funmilayo, Olikoye àti Beeko Ransome Kiuti?
Aworan Fela Kuti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ti a ba n sọrọ nipa idile lorilẹede Naijiria, ọkan gbọgi ni idile Kuti, ti wọn si jẹ ilumọka.

BBC tẹ ọkọ leti lọ niluu Abeokuta nipinlẹ Ogun nibi ti idile Kuti tẹdo si ati ibi ti kọ ile si, eyi lo fihan pe ilu Abeokuta ni idile Kuti ti wa.

Ile idile Kuti ti le ọgọrun ọdun bayii, ti ijọba si sọ ibi iko nnkan isẹmbaye si

Ọpọ awọn eeyan ni idile yii ni wọn jẹ ilumọka ati gbajumo lọrilẹede Naijiria, ti wọn si ti ko ipa ribiribi ninu dida asa ati ise ilẹ Yoruba.

Se ka sọrọ nipa Orin kikọ ni, eto ilera ni, jija fẹtọ ọmọniyan, ati bẹẹlọ, ẹbi Kuti ti se gudugudu meje yaya mẹfa.

Ta ni Josiah Jesse Ransome Kuti ati Fumilayo Ransome Kuti?

Olori idile naa, Josiah Jesse Ransome Kuti jẹ ọmọ bibi Egba ti wọn bi lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun 1855.

Olusọ aguntan ni Josiah, to si jẹ olori ile ijọsin Church Missionary Society ni ọdun 1871.

Isẹ olukọ ni Josiah fi bẹrẹ niluu Abeokuta sugbọn o pada fi isẹ naa silẹ , to si bẹrẹ si ni kọ awọn eeyan bi wọn se n kọrin.

Lara awọn ọkan lara orin ti Josiah kọ ni awọn Ẹgbam Isẹ Agbẹ ati Ẹjẹ ko ọmọde wa.

Josiah ku ni ọdun 1930 ni ẹni ọdun marinlọgọrin, to si fi ọmọ silẹ laye.

Amọ ko si bi a se fẹ darukọ eeyan ninu idile Kuti, ti a ko ni darukọ obinrin akikanju to jẹ obinrin akọkọ to wa mọto ayọkẹlẹ ni Naijiria.

Fela

Orukọ rẹ ni Mama Olufunmilayo Ransome-Kuti, orukọ ọkọ rẹ ai ni Oludotun Ransome Kuti.

Akọsilẹ wa pe Mama Funmilayo Ransome-Kuti lo lewaju awọn obinrin nilu Abeokuta, tii se olu ilu ipinlẹ Ogun bayii, lati tako owo ori sisan lasiko eebo amunisin.

Iwọde naa si rinlẹ debi pe ọrọ naa ni Alake to wa lori oye lasiko naa ba kuro lori itẹ.

Bakan naa lo tun maa n gbena woju awọn adari ilu tlọkan o jọkan, ti iwa rẹ yii si jẹ ko di ilumọọka.

Lara awọn to gbẹyin Josiah ni Fela Anikulapo-Kuti, Beko Ransome-Kuti, Olikoye Ransome Kuti, Professor Wole Soyinka, Femi Ransome Kuti ati Segun Kuti.

Ẹ wo fọnran yii lati mọ si nipa idile Kuti ti ilu Abeokuta