‘Ó lé ní àádọ́ta àwọn akẹgbẹ́ ẹ wa tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ọdún yìí nítorí àìlówólọ́wọ́’

Aworan awọn oṣiṣẹ ileẹkọ gbogboniṣe Rufus Giwa to n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn oṣiṣẹ ileẹkọ gbogboniṣe Rufus Giwa to wa nilu Owo, nipinlẹ Ondo lo ti ṣe iwọde ifẹhonuhan ni Ọjọru ọsẹ yii lati fi aidunnu wọn han lori bi awọn alaṣẹ ileẹkọ naa ṣe n jẹ wọn ni owo oṣu mẹwaa.

Awọn oṣiṣẹ ọun, labẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ nileẹkọ giga, NASU, ati awọn agba oṣiṣe nileẹkọ gbogboniṣe, SSANIP, ni wọn di ẹnu ọna abawọle ileẹkọ naa pa ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni o wọle tabi jade.

Alaga ẹgbẹ SSANIP nileẹkọ naa, Alhaji Nafiu Okoro, ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba wi pe iya ajẹkudorogbo lo mu ki awọn gbe igbesẹ naa ki ijọba lee da si wọn.

‘Iya diẹ kọ la n jẹ lati ibẹẹrẹ ọdun yii’

Okoro wi pe yatọ si oṣu mẹwa ti awọn alaṣẹ ileẹkọ naa jẹ wọn, wọn tu jẹ owo oṣu mẹfa ti wọn ya ninu owo ajọ alajẹṣẹku tawọn ọṣiṣẹ n da, leyi ti awọn alaṣẹ naa yọ lati bii ọdun mẹfa sẹyin leyi to jẹ nkan bii ẹẹdẹgbẹrin miliọnu naira.

“Ko ye wa bi wọn ṣe fẹẹ ka maa tọju ara wa ati awọn mọlẹbi wa pẹlu owo oṣu mẹwa ti wọn jẹ wa.

“Bi aṣe n sọrọ yii, nkan bii aago mẹwa ni pupọ ninu awọn oṣiṣẹ maa n de ibi iṣẹ latari pe ẹsẹ ni wọn fi n rin lati igboro nitori airowo ọkọ.

“Pupọ ninu wa lo wa lori idubukẹ aisan ti ọpọ si ti dero ọrun nigba ti won ko ri oo lati tọju ara wọn.

‘Oṣiṣẹ mẹta la sinku wọn laarin ọjọ mẹta nitori ọrọ yii’

“Nigba miran, mọlẹbi awọn to ba wa lori idubulẹ aisan yoo sunkun wa sinu ọgba yii, awa naa yoo tẹle wọn lọ ọdọ awọn alaṣẹ lati bẹbẹ fun owo ti wọn yoo fi tọju ẹni bẹẹ ninu owo to fi oogun oju rẹ siṣẹ fun, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

“Laarin ọdun yii nikan, o le ni aadọta ninu awọn akẹgbẹ wa ti wọn ti padanu ẹmi nitori ebi, aarẹ ti ko to nkan ati oniruuru ipenija miran ti wọn ko nii lee doju kọ to ba jẹ pe wọn ri owo oṣu wọn gba lasiko ni.

“Ninu ọdun yii, a sinku mẹta ninu awọn taa jijọ n ṣiṣẹ laarin ọjọ mẹta. Eyi jẹ ohun to buru jai ti ko yẹ ko maa ṣẹlẹ si ẹni to ba n fi ara ati ọkan rẹ sin ijọba.”

‘A o ti ilẹẹkọ yii pa nibẹrẹ ọdun tuntun”

Alhaji Okoro wi pe awọn ti kọwe ranṣẹ si gbogbo ẹka to yẹ ko de lọdọ ijọba, latori adele gomina ipinlẹ naa, Lucky Aiyedatiwa, to fi kari gbogbo aọn to nii ṣẹ pẹlu eto ẹkọ ninu igbimọ iṣejọba, ati igbimọ to n moju to eto ẹkọ giga nile aṣofin ipinlẹ naa.

“Koko ohun taa sọ fun wọn ni pe, ti wọn ko ba wa wọrọkọ fi ṣ’ada ki ọdun yii to pari, a o ti ileẹkọ yii pa, bẹrẹ lati ọjọ keji, oṣu kini, ọdun 2024.

“Iya ti wọn fi jẹwa ti to. Ao le maa ṣiṣẹ ka tun maa rare bi alainiṣẹlọwọ.

“Ti ẹ ba de aarin igboro ilu, ẹ maa ri bi awọn oṣiṣẹ ileẹkọ yii ṣe n tọrọ gbogbo nkan, wọn ti sọ wa di atẹwọgbọrẹ lai kii ṣe pe a o niṣẹ lọwọ.

‘Wọn le alaga ASUP tẹlẹ lọ nitori ọrọ yii’

Alaga ẹgbẹ SSANIP naa wi pe nitori ọrọ owo ti wọn jẹ awọn yii ni awọn alaṣẹ ileẹkọ naa ṣe le alaga ẹgbẹ awọn olukọ ileẹkọ gbogbonisẹ (ASUP) nileẹkọ naa tẹlẹ, Rafiu Ijawoye, sile lọdun diẹ sẹyin.

“ASUP chairman wa tẹlẹ, Rafiu Ijawoye, tori ọrọ yii ni wọn ṣe lee lọ ni 2019 nigba to n ja pe wọn ni lati san gbogbo owo ti wọn jẹ wa ki. Ẹnu ọjọ mẹta yii ni wọn too gbaa pada, bẹẹ ni wọn o tii san owo ọhun.

“Ṣe o di igba ti gbogbo wa ba ku tan ki wọn to ronu ati san owo ti wọn jẹ wa ni?”

Okoro fẹsun kan awọn igbimọ iṣejọba ileẹkọ naa pe niṣe ni wọn na owo to n wọle ninakuna.

O waa kesi ijọba lati gbe igbimọ kalẹ ti yoo yẹ iwe owo ileẹkọ naa wo, ki wọn si tun fi ọwọ osi juwe ile fun alaga igbimọ iṣejọba ilẹẹkọ naa nitori iwa jẹgudujẹra ati aibikita to n hu.

Awọn alaṣẹ ileẹkọ naa wi pe eto n lọ lati yanju gbogbo wahala ọhun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ fun ileẹkọ gbogboniṣe naa, Samuel Ojo, lakoko to n fesi si ibeere BBC Yoruba lori awọn ẹsun tawọn oṣiṣẹ fi kan awọn alaṣẹ ileẹkọ naa, wi pe ootọ ni awọn oṣiṣẹ naa sọ.

Ojo wi pe “ootọ ni pe owo oṣu o lọ deedee, bẹẹ si ni ti owo ‘deduction’ ti wọn n da funra wọn.

“Kii ṣe pe a n kawọ lewọ ti a n woran. A n gbiyanju, ki Ọlọrun fun wa ṣe.

“Bi wọn ṣe fi ẹhonu han yii, a fẹẹ ki a jọ joko sọ asọyepọ ka si wa ọna abayọ. O bani ninu jẹ pe nkan lee ri bayi, ṣugbọn a nigbagbọ pe taa ba jijọ joko pọ, yoo ni iyanju.

Lori ẹsun ti wọn fikan igbimọ iṣejọba ileẹkọ naa, Ojo wi pe “ẹsun lasan leleyi ti ko si iwadii kọkan nipa rẹ. Igbagbọ mi ni pe owo airigba yii ohunkohun lo lee bi nipa ki eeyan ka oriṣiriṣi ẹsun seeyan kan lẹsẹ.

Nibi gbogbo oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa ṣe bẹrẹ si nii ri owo oṣu kejila gba lati Ọjọru ọsẹ yii, igbagbọ awọn oṣiṣẹ ileẹkọ yii ni pe ijọba yoo ṣiju aanu wo wọn lati san diẹ lara owo ti wọn jẹ wọn kawọn naa o lee ṣe ọdun pẹlu idunnu lai wo ọwọ ọlọwọ.

Rufus
Rufus

Oríṣun àwòrán, bbc

Rufus
Rufus
rufus
Rufus
Rufus