Afurasí ọkùnrin tó f'ọ̀bẹ gún akọ̀wé kóòtú pa kó sí gbaga ọlọ́pàá

Aworan oga olopaa

Oríṣun àwòrán, Kayode Egbetokun/X

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Linus Dimas ni o ti bọ sọwọ ọlọpaa bayii lori ẹsun pe o fi ọbẹ gun akọwe ile ẹjọ pa.

Dimas ẹni ọdun mẹtalelogoji to n gbe ni Kugama Wuro ni ijọba ibilẹ Mayo Belwa nipinlẹ Adamawa ni a gbọ pe o kọ lati gba iwe ipejọ ti Yauba Usman lọ fun un.

Nigba ti Usman to jẹ oṣiṣẹ kootu agbegbe Nasarawo Jereng n fun Dimas ni iwe ipejọ ni a gbọ pe afurasi yii gun un lọbẹ leralera eyi to jẹ ki o farapa yanayana.

Bayii ni wọn gbe Usman digba digba lọ sile iwosan, amọ Ẹlẹmii ti gba a.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, SP Sulaiman Nguroje lo fi ọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Afolabi Babata ti pàṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.