Tani-Olohun àti àwọn Alfa Ilọrin ṣe ìpàdé àlàáfíà, ó ní kí wọ́n foríji òun

Abdulazeez Adegbọla ti wọn n pe ni Tani-Ọlọhun, agbẹjọro rẹ; Ademola Banks ati awọn molẹbi rẹ to fi mọ awọn olupẹjọ ti ko rawon jọ lati se ẹjọ ti wọn pe onisẹse naa ni tubi n nubi.
Awon Alfa ati onisẹse naa ko gbẹyin nibi ipade alaafia naa to waye ni inu ile ẹgbẹ awọn agbẹjọro Ilọrin, ipinlẹ Kwara loni ọjọ kọkandinlogun osu kejila ọdun yii.
Tani-Ọlọhun, ni oun jẹjọ ni ile ẹjọ mẹrin ọtọọtọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisun Kurani nina ti awọn mẹrin ọtọọtọ pee.
Awọn ti o pee lẹjọ ni ẹgbẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilorin), Alfa
Tonile Okutagidi, Sheikh Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ Modrasat Mohammed.
Nibi eto alaafia naa ni awon igun mejeeji ti jọ fenuko wi pe ki olujẹjọ naa bẹ awon ti o fẹnu tabuku lori ẹrọ ayelujara ki alaafia si jọba.
Tani-Ọlọhun ṣe bẹẹ gẹgẹ, o bẹrẹ ẹbẹ rẹ latori Emir ilu Ilọrin dori ẹgbẹ Ogo Ilorin, Modrasat Mohammed, Alfa Tonile Okutagidi, Sheik Labeeb Lagbaji ati gbogbo Musulumi aye pata.
Ipade naa lọ ni alaafia, ati irẹpọ laarin awọn ẹlẹsin Musulumi ati ẹlẹsin abalaye.
Awọn ẹlẹsin mejeji gbarawon ni iyanju lati maa gbe ni irẹpọ, ki wọn si ma tabuku ẹnikẹni.
Wọn ni ko si ija mọ wi pe ọrẹ loku ti wọn yoo ma ba ara wọn ṣe.
Awọn agbẹjọro to tun wa nibi ipade naa lati ri wi pe eto alaafia naa kẹsẹjari ni Omowe Ahmad Hussein Folorunsho popularly known as Saddam, Agbẹjoro US Imam, Ademola Ajasa, Kayode Olateju, Jimba
Awọn eyan pataki yoku ni, Oloye Awodele Ogundare, Balogun Ilu Isẹyin, Yeye Olokun Ajesikemi, Iya Afin Nafisat Adegbọla ati bẹẹ bẹẹ lọ
Lẹyin eyi, boya awọn olupẹjọ yoo lọ wọgi le ẹjọ ti wọn pe onisẹse naa tabi wọn yoo tẹ siwaju ku sọ wọn wọn ati ìpinnu ile ẹjọ labẹ ofin















