Àwọn àlùfáà ìjọ àgùdà le máa wúre fún àwọn lọkọlaya akọ sì akọ àti abo si abo- Pope

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pope Francis ti buwọlu pe ki awọn alufaa ijọ aguda lagbaye ni anfani lati maa gbadura fun awọn lọkọlaya akọ si akọ ati abo si abo.
Eyi lo jẹ ohun iwuri fun awọn eeyan LGBT ti wọn jẹ olujọsin ninu ijọ aguda.
Sugbọn o jẹ ko di mimọ pe iwure ko gbọdọ ni nkan se pẹlu ijọsin ninu ile ijọsin tabi ko fi ara pẹ igbeyawo.
Pope buwọlu ikede lọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023, to si ni eyi ti fihan gbangba pe Ọlọrun nifẹ si gbogbo eeyan.
Se ijọ Aguda ti wa fi ọwọ si igbeyawo akọ si akọ tabi ti abo si abo ni?
Poopu ni ile ijọsin aguda si ni igbagbọ pe laarin akọ ati abo nikan ni igbeyawo le waye ati pe iwure yii ni ko ni nkankan se pẹlu asa ati ise ile ijọsin naa lori igbeyawo.
Awọn alufaa ko ni anfani lati mura tabi pe ede ti wọn n lo fun igbeyawo fun awọn lọkọlaya akọ si akọ tabi abo si abo ti wọn n gbadura fun.
Atẹjade ti ile ijọsin Aguda fi lede salaye pe sise iwure awọn lọkọlaya ni o jẹ nnkan ti wọn gbọdọ se lati le mu ibasepọ awọn eeyan yii pẹlu Ọlọrun danmọran.
“A ko ni erongba lati fi aye silẹ fun igbayawo akọ si akọ tabi abo si abo sugbọn a gbọdọ jẹ ki wọn ni anfani si oore Ọlọrun, lati bere iranlọwọ ti yoo jẹ ki wọn gbe igbeaye to dara.
“Lati fun ẹmi mimọ laye lati jẹ ki ijinirere tẹsiwaju.”















