Àjọ SERAP sọ ìdí mẹ́ta tó ṣe wọ̀ àjọ INEC lọ síwájú ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Inec
SERAP, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan lorileede Naijiria ti pe ajọ eleto idibo Naijiria INEC lẹjọ lori ẹsun pe ko ribi seto bi awọn to kopa ninu iwa magomago lasiko idibo ṣe fẹ ni ifiyajẹ
SERAP sọ pe INEC ti kuna lati ṣe ojuṣe rẹ tori naa ile ẹjọ lọrọ kan lati jẹ ko ṣe nkan to ye.
Ajọ ajafẹtọ-ọmọniyan yi sọ pe ti awọn alaburu yi ba lọ lae foju wina ofin, yoo mu ki awọn mii gboya si lati tẹsiwaju lati maa hu iwa aburu.
Wọn ni ọrọ ti debi pe awọn kan a maa fa wahala l'awọn ibudo idibo tori wọn mọ pe wọn yoo wọgile esi idibo nitori iwa yii.
Kolawole Oluwadare to jẹ igbakeji oludari ajọ Serap sọ fun BBC pe awọn pe INEC lẹjọ tori iwe ẹhonu to pọ tàwọn alẹnulọrọ kọ lati kesi Inec ko ṣe ojuṣe rẹ.
O ni " Ojúṣe Inec ni ko wọ awọn to huwa janduku lọ siwaju ile ẹjọ.A fi iwe ranṣẹ si wọn lori ọrọ yi amọ aikọbiara si wọn lo mu ka gbe igbesẹ lati wọ Inec lọ sile ẹjọ ''
Ọgbẹni Oluwadare sọ pe igbesẹ t'awọn fẹ gbe yoo mu idagbasoke ba ijọba awaarawa ati eto idibo ki iru rẹ ma ba waye mọ.
Esi ti Inec fọ lori ọrọ yii
Ajọ eleto idibo ti sọ tiẹ lori ọrọ naa.
Wọn ni awọn gbe igbesẹ lati ṣe suuru ki wọn baa le mọ iru igbesẹ ti Serap fẹ gbe.
"Ojuṣe ajọ eleto idibo ni lati seto idibo amọ to ọrọ ba kan mimu awọn to tapa sofin lasiko idibo, ojuṣe awọn agbofinro leyi jẹ"
Bẹẹ ni alaye to wa lati ọdọ agbẹnusọ Inec Zainab Amunu.
O sọ pe " ti awọn agbofinro ni paapa awọn ọlọpaa ba mu eeyan to hu iwa ọdaran lasiko idibo wọn yoo mu iru eeyan bẹẹ ti wọn yoo si ṣe iwadii ki wọn to fi abajade iwadii ranṣẹ si ajọ eleto idibo"
O ni ti abajade yi ba fihan pe ẹni naa hu iwa ọdaran "igba naa ni Inec yoo gbe iru eeyan bẹẹ lọ sile ẹjọ tàwọn adajọ yoo si gbe idajọ to yẹ kalẹ."
Ajọ Serap ti yara ju lori ọrọ yi tori pe awọn ọlọpaa ko ti pari iwadii depo pe wọn yoo da esi pada sọdọ wa t'awa naa yoo si gbe igbesẹ to kan"
Arabinrin Zainab so pe afojusun Inec ni ki gbogbo awọn to hu iwa ọdaran koju ijiya lẹyìn ti iwadii ba fi han pe wọn jẹbi.
Ọrọ iwa ọdaran lasiko idibo jẹ nkan to gbode lẹka eto idibo Naijiria.
Eyi si n waye t'ohun ti pe wọn a maa pin awọn agbofinro kaakiri ibudo idibo lati le dena iru ìṣẹlẹ yi.












