Ṣé lóòótọ́ ní adelé gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo gbẹ́sé lé àsùnwọ̀n àwọn ìjọba ìbílẹ̀?

Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Others

Adele gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ti fesi lori iroyin to ni, o gbẹsẹ le apo asunwọn awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.

Bakan naa ni iroyin mii tun sọ pe Ọgbẹni Aiyedatiwa, da alamojuto iṣẹ́ fun Gomina Rotimi Akeredolu, duro.

Ọjọ Àbámẹta ni iroyin jade sita pe Aiyedatiwa pasẹ fun gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ, pe wọn ko gbọdọ gba owo jade, to si tun ni ni ki wọn o pa awọn asunwọn kan rẹ ni banki.

Sugbọn adele gomina sọ pe ayederu patapata ni awọn iroyin naa.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade ti kọmisanna fun eto iroyin, Bamidele Ademola-Olateju, fi sita lorukọ rẹ lọjọ Abamẹta.

Ọgbẹni Bamidele sọ pe ko si igba kankan ti adele gomina, pa iru àṣẹ bẹẹ.

O ni "a ti ko awọn oṣiṣẹ lọ si awọn ijọba agbegbe ti ijọba ṣẹ̀ṣẹ̀ da silẹ.

" Ọna ti idagbasoke yoo fi ba awọn ijọba agbegbe mẹtalelọgbọn tuntun, ati ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa tẹlẹ, ni ijọba n wa. "

Kọmisanna eto iroyin tun sọ pe bi ijọba ṣe ti da ọjọ fun idibo ijọba ibilẹ, naa ni ajọ eleto idibo nipinlẹ Ondo, ti n ṣe eto lori bi kanselọ marun-marun un yoo ṣe wa ni ikọọkan awọn ijọba agbegbe tuntun.

Igbesẹ naa lo ni o jẹ ara nnkan to yẹ ni ṣíṣe, ki awọn ijọba agbegbe tuntun naa le fi ẹsẹ mulẹ.

Yatọ si eyi, o ni adele gomina ko gba iṣẹ́ lọwọ olori awọn oṣiṣẹ to n ṣe amojuto bi gomina ṣe n gbalejo, ṣe ipade tabi lọ fun eto kankan.

Saaju ni iroyin sọ pe Lucky Aiyedatiwa da Ọgbẹni Bola Alabi duro.

Kọmisanna sọ pe titi di asiko yii, Ọgbẹni Bola ṣi n ṣe awọn nnkan naa fun gomina.

"Amọ adele gomina, Lucky Aiyedatiwa, yoo ṣe gbogbo ayipada to ba yẹ, lati mu ki iṣejọba ko rọrun."