Ìjọba Rivers da ilé aṣòfin wó bí Gómìnà Fubara ṣe ṣàgbékalẹ̀ ètò ìṣúná níwájú aṣòfin mẹ́rin péré

Aworan Gomina Fubara ati Minisita Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, GOVERNORNYESOMEZENWOWIKECON

Sinima fiimu to n waye nipinlẹ Rivers tun gba ọna miran yọ lowurọ Ọjọru pẹlu bi ọkọ katakata ṣe wo ile aṣofin ipinlẹ naa lulẹ.

Fonran fidio lati ipinlẹ Rivers lawn eeyan ri kaakiri oju opo ayelujara to ṣafihan bi wiwo yi ṣe n lọ.

Iṣẹlẹ yi n waye lẹyin ọjọ meloo kan tawọn ọmọ ile aṣofin mẹtadinlọgbọn ṣipo kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC.

Titi di akoko yi, ijọba tabi ẹnikẹni ko ti ṣalaye idi ti wiwo ile yi fi n waye lonii.

Bẹẹ naa tun ni a ri aworan to ṣafihan bi Gomina Siminalayi Fubara ti ṣe n ṣagbekalẹ iṣuna ọdun 2024 ni waju awọn ọmọ ile aṣofin mẹrin pere ninu ile ijọba.

Fakinfa laarin awọn ọmọ ile to ku ati Gomina ti to ọjọ mẹta to bẹrẹ ti ko si ṣẹyin bi wọn ti ṣe sọ pe awọn fẹ yẹ aga nidi rẹ ti Gomina si fariga pe ko si ohun to jọ ọ.

Wike ati Fubara, nibo lọrọ yi fẹ kangun si?

Ti a ba tu iṣu de isalẹ koko ko ni jẹ iyalẹnu pe aawọ laarin Gomina ati baba isalẹ rẹ Minisita olu ilu Naijiria, Nyesom Wike lo wa nidi gbogbo rogbodiyan to n waye ni ipinlẹ Rivers yi.

O ti to ọjọ mẹta tawọn mejeeji ti jọ n figa gbaga to si ti wa di ọrọ boo lọ o yago fun mi laarin awọn alatilẹyin wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Laipẹ yi ni awọn kan lọ dana sun ile aṣofin ipinlẹ Rivers nigba to jọ pe awọn aṣofin ṣetan lati dibo buwọlu ipinnu lati yẹ aga nidi Gomina Fubara.

Awọn ikọ mejeeji ti ọrọ kan n naka aleebu si ara wọn amọ loju aye, ko si ẹni to sọ pato awọn to wa nidi iwa yi.

Ọrọ ṣe bi ẹni pe o fẹ ẹ niyanju lẹyin ti aarẹ Bola Tinubu da si ọrọ yi amọ a n jẹ ekuru ko tan lawo lọrọ to wa nilẹ, awọn ti ọrọ kan ṣi n gbọn ọwọ wọn si inu awo.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Nyesom Wike ṣe pẹlu awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin Naijiria laipẹ yi lori ija oun ati Gomina Rivers bayii, Siminalayi Fubara, Wike to jẹ gomina ilu naa tẹlẹ, sọ pe oun ko fẹẹ sọrọ nipa rẹ.

O ni ṣugbọn ''bi eeyan kan ko ba ti i lowo ati ipo, iwa oniwa ni yoo ma hu.''

Wike sọ pe ''iwọ fun eeyan nipo agbara ati owo, igba naa ni wa a mọ iru ẹni ti i ṣe gan-an. Ti o ko ba ti i fun eeyan nipo ati owo, ma sọ pe o mọ ọn o’’

Wike sọ pe o ba ni ninu jẹ pe laarin oṣu mẹta pere, ẹnikan si foju oloore rẹ gungi lai bikita.

O ni Gomina naa kọyin sẹgbẹ oṣelu to ti i lẹyin to si gbe e depo.

Fubara fi ikini ku oriire ọjọ ibi ranṣẹ si Wike

Aworan afihan bi Gomina Fubara ṣe ki Wike ku orire ọjọ ibi

Oríṣun àwòrán, Siminalayi Fubara/X

Lowurọ kutu Ọjọru ti gbogbo sinima yi n waye ni Gomina ipinlẹ Rivers ti fi ikini ranṣẹ si ababa iṣalẹ rẹ pe o ku oriire ọjọ ibi rẹ.

Loju opo Twitter ni ikini yi wa to si mu iriwisi ọtọọt wa lọdọ awọn to ṣalabapade rẹ.

Bawọn kan ṣe n sọ pe oju aye lasan ni Gomina n ṣe lawọn mii n kan sara si pe ọlọgbọn eeyan lo jẹ pẹlu bo ṣe n fẹjẹ sinu to si n tutọ funfun jade.

Nilu Abuja bakan naa , awọn ọmọ ile aṣofin lati ipinlẹ Rivers kan kora jọ lati ṣe abẹwo ikini ku oriire Wike lọjọ ibi rẹ.

Aworan ọrọ ti awọn kan sọ nipa Fubara ati Wike ni Twitter

Oríṣun àwòrán, @JustKings

Ta ni yoo pada wa bori laarin Wike ati Fubara?

Ija laarin Gomina ati awọn baba isalẹ ti wọn gbe wọn de ori ipo ko jẹ tuntun ni Naijiria.

Lọpọ igba araalu lo maa n fori ko wahala ija yi tawọn mejeeji a si pada wa pari ẹ laarin ara awọn.

Amọ eyi to pọ to maa n 'sẹlẹ ni pe eeyan kan a fẹnu gbole ti eyi a si maa saba jẹ baba isalẹ to fi Gomina jẹ.

A ri apẹrẹ tọka si bii ti Gomina nigba naa Rotimi Amaechi to bori ija laarin rẹ ati baba isalẹ to gbe de ipo Odili.

Wike gaan fun ara rẹ naa ni aawọ pẹlu Rotimi Amaechi bo ti lẹ jẹ wi pe Wike a maa sọ pe Amaechi ko lọwọ ninu boun ṣe de ipo Gomina.

Wike lo pada bori Amaechi ninu ija yi.

Gomina Obaseki ipinlẹ Edo ati baba isalẹ rẹ Adams Oshiomole naa pada ja si pe Obaseki lo bori.

Koda ni ipinlẹ Kano, Gomina Umar Ganduje ati oloore rẹ Kwankwanso naa koju ara wọn.

Ganduje lọwọ bayii lo dabi ẹni pe o n rọwọ mu.

Diẹ la le ka ninu awọn ti ko ribi bori baba isalẹ wọn bii Gomina Akinwumi Ambode ipinlẹ Eko ati Gomina Oyetola ipinlẹ Osun to fidirẹmi nigba ti ija waye laarin awọn ati baba isalẹ wọn.