Owó tí wọn pín kàn wa nínú èto ìṣúná 2024 kò lè dẹ́kun ìṣẹ́ àti òṣi ní Nàìjíríà -Mínísítà figbe ta

Aworan Minister Betta Edu

Oríṣun àwòrán, FMHAPA

Minisita to n dari ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto ọrọ irọrun nipa ipese iranwọ lẹyin isẹlẹ pajawiri fun awọn ara ilu, Dokita Beta Edu ti sọ pe iye owo ti wọn ya sọtọ fun ileeṣẹ rẹ ninu eto iṣuna ọdun 2024 ko le to lati koju ipenija iṣẹ ohun oṣi.

Minisita fọrọ yi lede lasiko to wa siwaju ile aṣofin lati wa ṣalaye iye ti ileeṣẹ rẹ fẹ na fun ọdun 2024.

Sẹnẹtọ Idiat Adebule lalaga igbimọ apapọ ile to n mojuto ọrọ irọrun nipa ipese iranwọ pajawiri.

Gẹgẹ bo ṣe wi, wọn fun ileeṣẹ rẹ ni gbendeke owo ina biliọnu N532.5 to ṣe deede ida mejidinlọgbọn alekun to waye ju ti ọdun 2023 lọ gẹgẹ bi na ati koju ọwọngogo to ba ọrọ aje.

Edu sọ pe alekun yi ko to lati koju alekun nkan lọja to jẹ ida 27.33 ninu ida ọgọrun ti Naijiria n koju lonii.

Bẹẹ lo sọ pe owo ti wọn la kalẹ fun owo ina iṣẹ agbaṣe ni wọn ti dinku lati biliọnu mẹta Naira le ni ọdun 2022 si biliọnu kan le diẹ ni 2023.

Adinku yi ṣe dede ida mkanlelaadọrin ninu ida ọgọrun.

Betta Edu sọ pe ''gbendeke iye owo ina iṣẹ agbaṣe biliọnu kan le diẹ ti wọn fi kun ninu owo iṣuna ọdun yi ko le to afojusun ileeṣẹ yi lati dẹkun oṣi lorileede Naijiria''

Ẹ wo ti awọn ọmọ Naijiria ti oṣi n ba finra - Betta Edu

Minisita rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ igbimọ ati alaga wọn lati da si ọrọ yii ki wọn si wo tawọn ọmọ Naijiria ti nkan ko rọgbọ fun.

''Ori wa ni bukata kikoju iṣẹ pẹlu ododo da lori.Nkankan ti awa taa n ṣiṣẹ labẹ idari aarẹ Tinubu fi skan si ni pe a fẹ yọ awọn ọmọ Naijiria kuro ninu ọọfin iṣẹ.''

''Bi wọn ko ba ṣe iṣuna fun, a ko ni le ribi ṣe eto taa fẹ ṣe''

Alaga igbimọ naa, Adebule beere lọwọ Minisista naa boya o ṣagbekalẹ iṣuna yi nigba ti wn fi n ṣe eto iṣuna nibẹrẹ pẹpẹ.

Minisita fesi pada pe awọn ṣagbekalẹ rẹ ṣugbọn wọn ko gbe jade ninu iṣuna ti wọn pada ṣiro fun ileeṣẹ wọn.

Ninu akọsilẹ ti ajọ aṣeṣiro Naijiria gbe sita lori awọn ọmọ Naijiira ti ko rọwọ mu bẹnu, wọn sọ pe ida mẹtalelọgọta eeyan ninu ida ọgọrun loṣi n ba finra.

Iṣiro yi jẹ eeyan miliọnu mẹtalelaadoje