Àlàyé rèé lórí bí ọ̀wọ́ngógó Náírà ṣe ń tẹ̀síwájú làwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ ọmọ Naijiria ni paapa awọn to n ṣowo pẹlu POS ko dakẹ ariwo airowo lawọn ipinlẹ kọọkan.
Eyi n waye tohun ti bi banki apapọ Naijiria CBN ṣe ni ki araalu ma foya wi pe ọrọ airowo nita faraalu ko ṣẹyin awọn kan to n ko owo naa pamọ.
Cbn tun di ẹbi iṣẹlẹ yi ru awọn to ni wọn gba owo pupọ jade nile ifowopamọ.
Ni bayii, awọn to n ṣowo POS ti wa sọ pe awọn ile ifowopamọ ti mu adinku ba iye owo ti wọn n fun awọn debi pe ko to ida mẹwaa ninu ida ọgọrun nkan tawọn gba tẹlẹ.
O ti n sunmọ ọdun kan bayii ti awọn ọmọ Naijriia koju ọwọngogo owo Naira lẹyin ti banki apapọ kede pe awọn fẹ mu iyipada ba Naira.
Eleyi si mu ki iye owo to wa nita dinku ti ọwọngogo Naira si waye jakejado Naijiria.
Botilẹ jẹ wi pe nkan tawọn araalu n koju bayi ko to ti ọdun 2022, kini naa n buru si tori pe ọdun ti n lọ sopin ati pe asiko yi lawọn eeyan a maa ṣe inawo pupọ.
Awọn onwoye ati awọn oniṣowo POS taa ba sọrọ da ẹbi iṣẹlẹ yi ru awọn ile ifowopamọ ati awọn kọọkan ninu awọn oniṣowo.
500,000 lojumọ tẹlẹ ti di 50,000 taa n ri gba ni banki-Awọn oni POS lọgun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Lọpọ ibi , owo gbigba lati ọdọ awọn oniṣowo POS lọna tawọn eeyan fi n ri owo gbọ bukata karakata ni Naijiria tohun ti pe ọpọ ile ifowopamọ lo ni aaye igbowojade taa mọ si ATM.
Cbn buwọlu gbigba owo lọdọ awọn oni POS yi gẹgẹ bi na ati mu adinku ba gbigbe owo pupọ rin kaakiri.
Eleyi jẹ ọna kan gbogi to mu iyipada ba ẹka idokowo Naijiria
Labẹ ilana yi, awọn ileeṣẹ tabi oniṣowo yoo forukọsilẹ lọdọ ile ifowopamọ to ba wu wọn ti wn yoo si maa ri owo gba jade ju awọn to ni akanti lọdọ ile ifowopamọ naa.
Tori naa, gbogbo igba tawọn oniṣowo POS ba ti n koju airowo gba jade ni ile iufowopamọ, o di dandan ki araalu naa mọ lara tori pupọ lo maa n gba owo lọdọ wọn.
Ibrahim Abdullahi to n ṣowo POS sọ fun BBC Hausa ni Abuja pe ''Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ni wọn maa n fun wa lojumọ tẹlẹ amọ bayii o ti di ẹgbẹrun lọna aadọta Naira taa n ri gba.''
O fikun pe awọn to forukọ silẹ gẹgẹ bi onibara pataki a maa ri gba to ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira gba amọ oun ko si lara wọn.
''Nilẹ oni to mọ ti mo lọ si banki,mi o ri gba to ẹgbẹrun lọna aadọta Naira.Iroyin taa n gbọ ni pe awọn ti kii ṣe onibara banki ko le ri gba ju ẹgbẹrun mẹwaa tabi ẹgbẹrun lọna ogun Naira gba jade''
Ki lo n fa ọwọngogo Naira?
Ọpọ awọn onwoye lẹka eto ọrọ aje sọ pe awọn idi kan lo fa sababi ọwọngogo yi.
Amọ ero wọn papọ pe banki apapọ, Cbn, awọn ile ifowopamọ ati awọn to n ṣowo naa lẹbi ninu ọrọ yi.
Bẹẹ naa ni wọn sọ pe iyipada Naira ọdun 2022 ṣi n dakun aisowo jakejado Naijiria tohun ti pe Cbn kede pe kawọn eeyan ṣi maa na owo tuntun ati ti tẹlẹ lọ.
Igbimọ awọn oniṣowo ile ifowopamọ taa mọ si Bankers Asociation s pe awọn ko ri alaye gbọ lọdọ awọn alaṣẹ lori idi ti owo yi fi wọn nita.
Amọ ṣa ọkan lara awọn ọga agba ẹgbẹ naa s fun BBC pe ''apẹrẹ taa n ri ni pe Cbn fi ki awọn araalu maa lo eto inawo ''cashless'' lalae bikita boya asiko rẹ to tabi ko to''
Aarẹ ẹgbẹ awọn to n ṣe idokowo owo ni Naijiria Salihu A Umar sọ pe ipenija airi owo yi pọ lawọn ipinlẹ bi Kano ati ilu Abuja.
''Awn eeyan kan ti n ko owo yi pamọ tori pe wọn lawọn ile ifowopamọ naa ti n wawọ mọ owo yi.Wn ni awọn naa ni ohun tawọn fẹ fi owo ṣe lo jẹki awọn wawọ mọ eyi to wa lọwọ wọn''
Oniṣowo POS kan ni Kano Shuaibu Abdullahi sọ pe ọrọyi jọ bẹ tori awọn oniṣowo kan wa to ṣe pe wọn a maa ko owo pamọ de awọn onibara wọn to n ṣowo POS ti wọn a si ko owo fun wọn ki wọn baa le fi ṣowo pẹlu araalu.
''Kii ṣe gbogbo eeyan lo n ko owo wọn pada lọ si banki,awọn kan a tiẹ sọ fun ẹ pe awọn ni alabara oni POS tawọn n kowo fun lojojumọọ''
Salihu Umar sọ pe awọn oni POS yi tun maa n lọ si ile epo ati awọn ọja lati lọ gba owo lọdọ oniṣowo dipo ki wọn lọ si banki.















