Ẹ má ṣe àṣìṣe láti dìbò yan àwọn apààyàn lọ́dún 2023 – Jonathan

Oríṣun àwòrán, @GEJonathan
Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan ti kilọ fun awọn araalu lati maṣe dibo yan awọn apaayan ninu eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2023.
Jonathan lo sọ ọrọ naa niluu Uyo nibi isin idupẹ ọdun marundinlogoji ti wọn da ipinlẹ naa silẹ.
O ni “Lọdun 2023, ẹ ma ṣe aṣiṣe lati dibo yan awọn apaayan sori ipo.”
“Awọn ti wọn n ko ibọn, ọbẹ atawọ ohun ija oloro mii nitori oṣelu, ọta araalu ni wọn jẹ.”
“Ẹni to ba gbẹmi eeyan lati de ipo oṣelu yoo tẹsiwaju lati maa gbẹmi eeyan lati di ipo naa mu ni.”
“Ẹri daju pe lati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ, titi de ile igbimọ aṣofin aaab ati gomina, e dibo yan ẹni to tọ ni ipinlẹ Akwa Ibom.”
Aarẹ ana ọhun gboriyin fun gomina ipinlẹ naa, Udom Emmanuel, fun akitiyan rẹ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ naa.
Jonathan sọ pe Emmanuel ti ṣe daadaa lati mu igba itura de ba awọn eeya ipinlẹ rẹ lati ọdun meje to ti wa lori alefa.
O ni bo ti tilẹ jẹ pe oṣiṣẹ banki ni gomina ọhun tẹlẹ, ti ọpọ eeyah si lero pe ko ni ṣe daadaa gẹgẹ gomina, amọ o jọ awọn ti ko gbagbọ ninu rẹ loju.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ igbimọ ijọba ipinlẹ ọhun fun atilẹyin wọn fun gomina naa, eyii to mu ko ṣe aṣeyọri.














