Àwọn agbésùnmọ̀mí kọlu Mọ́ṣáláṣí, wọ́n pa àwọn olùjọsìn tó lé ní Mọ́kànlá

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Iṣẹlẹ naa sẹlẹ lọjọ Ẹti to kọja yii ti awọn ara adugbo ti wọn jẹ ẹlẹ́sìn Musulumi kórajọ lati lọ kirun Jimoh.
Kò dín ní eeyan mọ́kànlá ti iroyin ni awọn agbesunmomi ti pa bi wọn ṣe kọlu Mọsalasi kan ni ilu naa, Ruwan Jema ni ijọba ìbílẹ̀ Bukkuyum, Ìpínlẹ̀ Zamfara.
Olùgbé Bukkuyum kan, Salisu Ibrahim sọ fawọn oniroyin pé àwọn agbesunmomi naa ṣàdédé ya wọ ilu awọn loru ọganjọ ti wọn si lọ taara si Mọsalasi ilu naa nibi ti awọn eeyan ti kórajọ si fun àdúrà.
Ó ṣàlàyé pe "ṣe ni wọn ṣina ìbọn b'olẹ̀ si awọn to n kirun, wọn pa eeyan mọ́kànlá ti ọpọlọpọ si fara pa.
Ibrahim tun sọ pe awọn agbesunmomi naa tọ gbogbo ilu ka ti ìgbàgbọ́ si wa pe awọn araalu miiran ku amọ ti iye wọn ko tii dájú.
Koda o ni iye àwọn tí wọ́n pá nínú Mọsalasi gaan ko tii dájú.
O ṣàlàyé pé wọ́n ti kọkọ́ rò pé èèyàn meedogun ni wọ́n pa ṣùgbọ́n wọ́n padà ríi pé mẹ́rin lára wọn fara pa ni.
Ẹlòmíràn tó ń gbé ní ìlú náà sọ pe awọn fura pe ẹsan ni awọn agbesunmomi naa gba torí àwọn fijilante ilu ti wọn saba maa n pe ni Yan Sakai pa meji lara awọn agbesunmomi naa laipẹ yii.́
Ẹwẹ, agbenusọ Ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Zamfara, SP Mohammed Shehu fi aridaju han pe lóòótọ́ ni iṣẹlẹ naa sẹlẹ amọ o ṣàlàyé pe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye awọn ti wọn pa ko tii dájú.
Bẹẹ si ni o sọ pe awọn ti ran ikọ ọlọpaa lọ si ilu naa fun ayẹwo kíákíá ati pe wọn yoo gbe ẹkúnrẹ́rẹ́ iroyin síta to ba yá.















