Ka àlàyé tí iléeṣé ọlọ́pàá Èkó ṣé nípa nkán ìjà oloro tí wọn rí nínú bọ́ọ̀sì méjì ní Ikorodu

Aworan awọn afurasi ti ọlọpaa mu

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceNG

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti mu alaye bẹnu lori aworan ati fidio to gbode nibi ti wọn ti ṣafihan ọkọ akero kan ti nkan ija olori wa ninu rẹ.

Iṣẹlẹ yi waye ladugbo Ijede ni ilu Ikorodu lọjọ Abamẹta.

O si jẹ nkan to ya ọpọ lẹnu ni paapa pẹlu bi ko ṣe pe si asiko ti ọlọpaa ati ajọ NDLEA mu awọn afurasi kan ni Ikorodu ti wọn gbe oogun oloro coacaine to to nkan bi toonu 1,855.

Ninu ile ikẹrupamọsi kan ni wọn ti ba oogun oloro yi ni Ikorodu.

Amọ ṣa ni ti awọn nkan ija oloro ti wọn ri, ni ọjọ Abamẹta ni alukoro ọlọpaa Benjamin Hundeyin fi atẹjade sita pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

O ni awọn ba ọta ibọn ati nkan ija oloro wọnyi ninu bọọsi meji ti awọn afurasi fẹ fi ko wọn lọ si ipinlẹ mii ni apa ariwa Naijiria.

Ohun ti alukoro ọlọpaa sọ

Aworan ọta ibọn ti ọlọpaa ba lọwọ awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceNG

Benjamin Hundeyin ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikorodu lo mu awọn afurasi yi.

O ni wọn mu awọn mẹta yi to fi mọ awakọ ọkọ naa to sọ pe ipinlẹ Katsina lawọn n gbe ẹru inu ọkọ naa lọ.

Hundeyin ko sọ bi ọta ibọn ti wọn ri ṣe pọ to amọ o ni' "awọn agbofinro ọtẹlẹmuyẹ wa ni Ikorodu ribi da awọn afurasi to gbe ọkọ akero meji lọna ti wọn si ko nkan ija oloro sinu ọkọ wọn.''

O tẹsiwaju pe' "a tun ba alupupu ti wọn ti tu kalẹ sinu ọkọ naa ati awọn nkan ini ero inu ọkọ naa ni adugbo Ijede Ikorodu''.

O ni iwadii ibẹrẹ fi han pe Katsina ni wọn n ko awọn nkan wọnyi lọ.

Hundeyin ni awọn ti fa awọn afurasi naa le olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọwọ fẹkunrẹrẹ iwadii.

Awọran ọkọ ti wọn ko nkan ija si

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceNG

Aworan ọkọ ti wọn ko nkan ija oloro si

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceNG