Ìdí tí mo fi dákẹ́ lóríi ìdàrúdàpọ̀ inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nìyìí - Saraki

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Adari ile igbimọ aṣofin àgbà tẹ́lẹ̀ rí, Sẹnetọ Bukola Saraki ti pada sọ̀rọ̀ soke lẹyin ọpọlọpọ asiko to fi jawe mẹ́nu lai da si gbogbo onírúurú ija ohun ìdàrúdàpọ̀ to n rọ lu ẹgbẹ́ Peoples Democratic Party, PDP.
Saraki ṣẹ̀ṣẹ̀ de lati isimi ọlọdọọdun rẹ ni to si lọ si ìpínlẹ̀ Akwa Ibom taara lati dára pọ mọ ayẹyẹ ọdun ikarundinlọgbọn ìpínlẹ̀ náà.
Saraki ni oun ti n ṣiṣẹ́ lai pariwo to si fi kun un pe àwọn àkókò kan wa to yẹ keeyan máa ṣe bẹẹ.
Kii ṣe iroyin mọ pe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP eyi ti Saraki jẹ ọkan ninu wọn ti n koju ìṣòro laarin awọn adari pàápàá eyi to gba ẹnu gbogbo eeyan kan bayii ti wọn n sọ̀rọ̀ ẹ ìyẹn ipe nihin lọhun fun ikọwe fipo silẹ alaga ẹgbẹ́ naa, Iyorchia Ayu, pàápàá to jẹ wipe Gomina Ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike àti akẹgbẹ́ rẹ ni Oyo, Seyi Makinde n dari ipe fun ki alaga wọn fipo silẹ.
Bakan naa ni igun ti Gomina Nyesom Wike ṣẹ̀ṣẹ̀ yọra kuro lara igbimọ ìpolongo fun oludije Ààrẹ, Atiku Abubakar.
Bo tilẹ̀ jẹ pe oguna gbongbo ni Atiku jẹ ninu ẹgbẹ́ òṣèlú naa, o gbiyanju lati ma dára pọ mọ iha kankan yala awọn to n pe fun ikọwefipo silẹ Ayu tabi awọn ti ko pe fun un.
Àmọ́ Aiku ni tìrẹ ṣaa tẹnu mọ pe ofin ẹgbẹ́ ni ki wọn tẹle.
Laipẹ yii naa, Atiku sọ pe ko si ẹni to lee fi tipátipá ni ki Ayu kọ̀wé fipo silẹ.
Eyi si da lori bí Wike ṣe tesiwaju ninu onírúurú ifọrọwanilẹnuwo to si n fẹ̀sùn fifun ati gbiga abẹtẹlẹ kan an to fi mọ oniruuru ẹ̀sùn míì.
Ki nidi ti awọn kan n fẹ́ ki Iyorchia fipo silẹ, ki ni ẹṣẹ rẹ?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọ̀ràn akobani kọ ni Iyorchia da kii sii ṣe pe o tapa si ofin amọ awọn ti ko fẹẹ yii ni awọn mọ ohun ti awọn n ja fun.
Wọn ni lori ọrọ ẹkùn ni, ti awọn si n fẹ́ ki ẹkùn Guusu di ipo to ṣe koko mu ninu idari ẹgbẹ́ náà.
Ẹwẹ, ohun ti Saraki sọ loju opo ayélujára Facebook rẹ ni pé:
"... Bi mo ṣe n lọ kaakiri orileede ni ọjọ díẹ̀ sẹ́yìn, mo ni imọlara pe ọpọlọpọ eeyan lo fẹ mọ idi ti mo fi dákẹ́ lori awọn ìgbésẹ to waye ninu ẹgbẹ́ wa, PDP. Idahun mi ni pé, àwọn asiko kan wa to yẹ keeyan sọ̀rọ̀ ki wọn si gbọ́ eeyan bẹẹ si ni asiko tun wa to jẹ pe ṣíṣe iṣẹ lábẹ́lẹ̀ lo máa n so eso rere." Saraki ni iru asiko bẹẹ nìyí.
Pẹlu bo ṣe loun duro gidigba sẹ́yìn Atiku, Saraki ni "PDP àti Atiku Abubakar ṣi ni ipinu to dara ju fawọn ọmọ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023!".















