A kò le gba ẹ̀bẹ́ Oyetola láti gbé ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Osun wá sí Abuja - Iléẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Adele ati Oyetola

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun to kalẹ silu Abuja ti fi aake kọri lati gba ẹbẹ Gomin ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola lori igbẹjọ nipa awuyewuye ibo gomina to kọja nipinlẹ naa.

Oyetola lo tọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun naa pe ko pasẹ ki wọn gbe igbẹjọ igbimọ to n gbọ awuyewuye to suyọ nidi esi ibo gomina to kọja nipinlẹ naa, wa maa joko nilu Abuja.

Ọjọ Kẹtalelogun osu kẹjọ ọdun 2022 si ni gomina Oyetola gbe ẹbẹ rẹ naa kalẹ siwaju aarẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun naa,Adajọ M.B Dongban Mensem, lati ipasẹ iwe kan ti agbẹjọro rẹ kọ si.

Alaye Oyetola ninu lẹta to fi gbe ẹbẹ naa kalẹ ni pe nitori eto aabo ti ko peye, yoo dara to ki igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo naa maa joko gbọ ẹjọ naa nilu Abuja.

Alaye ree lori idi ti a ko fi le buwọlu ẹbẹ Oyetola - Ile ẹjọ Kotemilọrun

Amọ nigba to n fesi lori lẹta ọhun, ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ni eyi ko ni le seese nitori awọn ileesẹ agbofinro ti leri leka lati pese aabo to yẹ fun igbimọ olugbẹjọ naa.

Lẹta kan ti ileẹjọ Kotẹmilọrun naa fi fesi pada ni Akọwe ileẹjọ naa, Bangari Umar fọwọsi, to si fi sọwọ si agbẹjọro fun gomina Oyetola, agba amofin Lateef Fagbemi .

Akori lẹta naa lo ni “RE: PETITION NO, EPT/OS/GOV/01/2022, ADEGBOYEGA ISIAKA OYETOLA & ANOR V. INDEPENDENT NATIONAL ELECTORAL COMMISSION & 2 ORS”.

 Ọjọ Aje, ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹsan ọdun 2022 yii si ni ile ẹjọ kotẹmilọrun naa kọ lẹta naa lati fesi pada nipa esi ibo gomina ipinlẹ Osun to waye lọjọ Kẹrindinlogun osu keje ọdun 2022.

Ileẹjọ Kotẹmilọrun naa tọkasi pe lẹyin ifikunlukun to yẹ, ati agbeyẹwo ẹbẹ Oyetola, aarẹ ile ẹjọ naa ko ni le buwọlu ẹbẹ rẹ.

Aarẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun naa ni “Awọn ileesẹ agbofinro to wa nipinlẹ Osun ti mu da ile ẹjọ yii loju nipa ifọwọsowọpọ ati atilẹyin wọn lati se amugbooro ipese eto aabo to yẹ fun igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo lasiko awọn ijoko rẹ gbogbo.”

Iwe ti ile ẹjọ Kotemilọrun fi fesi pada

Oríṣun àwòrán, Other