Ààrẹ Buhari Kan sáárá sí Ọọni Ife lórí ipa rẹ̀ sí ìṣọ̀kan Nàìjíríà

Àwòrán Ààrẹ Buhari àti Ọọni Ife

Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa fun yin in pe Ọọni fẹ bẹrẹ igbele ọlọjọ meje ni eyi to n bẹrẹ ayẹyẹ ọdun Ọlọ́jọ́ níbi ti yóò ti bẹ àwọn alálẹ̀ lọ́wẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.

Ní báyìí ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́ ti kásẹ̀ nílẹ́ tí Ọọni sì ti jáde padà lẹ́yìn ìgbélé ọjọ́ méje.

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kan sáárá sí Ọọni Ile Ife, Ọọni Enitan Ogunwusi Ojaja Keji fún ipa ribiribi tó ń kó sí ríri dájú pé àláfíà ń jọba ní agbègbè rẹ̀.

Ààrẹ Buhari, ẹni tí Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Rauf Aregbesola ṣojú fún níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́ ti 2022 ní ètò ààbò ní Nàìjíríà ti kọjá ohun tí ẹnìkan tàbí ìjọba le dá ṣe.

Ó ní níbi tí Nàìjíríà dé dúró báyìí, gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ máa wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọrí kí wọ́n yé dá gbogbo rẹ̀ dá àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nìkan.

“Ìjọba máa gbìyànjú láti ṣe ipá tirẹ̀ láti dá ààbò bo àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ kí àwọn ènìyàn máa ran àwọn òṣìṣẹ́ ààbò lọ́wọ́ kí iṣẹ́ wọn le jẹ́ àṣeyọrí.”

“Gbogbo àwọn ìwà kò tọ́ àti ìrìn tí kò bá mọ́ ti ẹ́ ba kẹ́fin ní àdágbò yin ló yẹ kí ẹ máa fi tó ìjọba léti.”

Ààrẹ ní òun gbóríyàn fún Ọọni fún ipa takuntakun tí Ọọni láti wá ojútùú sí ìpéníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lásìkò yìí.

Aregbesola àti Ọọni Ife níbi ayẹyẹ ọdun Ọlọ́jọ́

Ààrẹ rọ àwọn ènìyàn láti mú iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ọ̀kúnkúndùn

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọdún Ọlọ́jọ́, Ààrẹ ní láyé àtijọ́ ọdún Ọlọ́jọ́ àti àwọn ayẹyẹ mìíràn nílẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò tí wọ́n máa ń fi èrè oko wọn han aráyé.

Ó ní yàtọ̀ sí wẹ̀jẹmẹ̀mu tó máa ń wáyé láwọn àsìkò náà, iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ iṣẹ́ kan gbòógì tí Yorùbá kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú máa ń jẹ́ lájọrí ohun tí àwọn ayẹyẹ náà máa ń dálé lórí.

Ó fi kun pé yóò jẹ́ ìdùnnú àti ohun ìwúrí fún òun tí àwọn ènìyàn bá le padà sóko bí ti ayé àtijọ́ tí ọdún Ọlọ́jọ́ yóò sì máa jẹ́ ayẹyẹ tí àwọn àgbẹ̀ ti ń ṣàfihàn èrè oko wọn.

Ọọni àti àwọn èrò níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́

A máa fi ọdún Ọlọ́jọ́ wá ojútùú sí ìpèníjà ààbò àti ọrọ̀ ajé Nàìjíríà - Ọọni

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Ọọni Ogunwusi kọminú lórí àwọn ìpèníjà tó ń bá Nàìjíríà fínra pàápàá lórí ọrọ̀ ajé àti ètò ààbò.

Ọọni ní ohun ìbànújẹ́ ló máa ń jẹ́ fun òun nígbà tí òun bá ń kà ìròyìn nípa bí ètò ààbò ṣe ti fẹ́ pín Nàìjíríà sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

Ó ní gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò kọjá bí Nàìjíríà yóò ṣe pín lọ.

Ó wá sọ àrídájú rẹ̀ pé òun kò ní yẹ̀bá nídìí ríri dájú pé ìṣọ̀kan Nàìjíríà dúró ṣinṣin nípasẹ̀ lílo àṣà àti ìnàjú láti fi gbogbo ẹ̀yà mọ́ra.

Ọọni tẹ̀síwájú pé ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọ̀nà kan tí òun ní èròńgbà láti fi mú ìṣọ̀kan dúró láàárín gbogbo ènìyàn.

Ó fi kun pé gbogbo agbára òun ni òun yóò sà láti ri pé ìpìlẹ̀ rere tí àwọn ara ìgbà nnì fi lélẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Àrólé Oduduwa, kò parẹ́ rárá.

Ooni Ogunwusi fẹ́ bẹ alálẹ̀ lọ́wẹ̀ lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU

OONI ILE IFE

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti kuro ni aafin rẹ lati lọ da nikan wa, ko le bawọn alalẹ sọrọ, bi ọdun Ọlọ́jọ́ ṣe n sunmọ tosi.

Igbele adura naa ti Ooni yoo se fun ọjọ meje, lo jẹ ara igbesẹ to maa n waye saaju ọdun Ọlọjọ́ naa, eyi to maa n waye ni ọdọọdun.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lasiko tó ń kúrò ní ààfin Ile-Oodua, Ooni ní bí òpin yóò ṣe dé bá ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé, wà lára àdúrà tí òun yóò máa bá Olódùmarè sọ.

Ọọni ní bí àgbọ́yé yóò ṣe wà láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, ASUU àti ìjọba àpapọ̀ wà lára ohun tí òun yóò máa bẹ àwọn alálẹ̀ lọ́wẹ̀, sí bí òun ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìgbélé ṣaájú ọdún Ọlọ́jọ́.

Ooni ní òun máa fi àkókò ìgbélé náà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lórí gbogbo ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pàápàá bí ètò ìdìbò gbogbogboò ṣe ń kan ilẹ̀kùn gbọ̀ngbọ̀n.

 Ó ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀, ní kíákíá gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ náà bí wọn kò bá fẹ́ rí ìbínú àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.

 Ó ní àwọn ọ̀dọ́ ti ń bínú gidi lọ́wọ́ yìí tí ènìyàn kò sì le rí wọn báwí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ni wọ́n ti fi wà nílé láì ṣe ohunkóhun.

 "ASUU àti ìjọba àpapọ̀ láti fẹnukò kí wọ́n fòpin sí ìyanṣẹ́lódì nítorí kò sí ẹni tó máa rí àwọn ọ̀dọ́ mú tí wọ́n bá bínú tán.

OONI ILE IFE

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọọni fi kun pé ìbínú àwọn ọ̀dọ́ ti ń fojú hàn nípa bí wọ́n ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dí ọ̀nà mọ́ àwọn ọlọ́kọ̀ ní àwọn òpópónà àti pápá kọ̀ òfurufú.

 Ó ní èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ti sún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ohun kan ògiri ló fa ìgbésẹ̀ wọn yìí.

 Ó ní lásìkò ìgbanisíṣẹ́ OjajaMore tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀, Ọọni ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò tíì parí ẹ̀kọ́ wọn ni àwọn tó forúkọ sílẹ̀ jùlọ.

 Ọba alayé ọ̀hún ní ohun tó túmọ̀ sí ni pé ilé ti sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ilé-ẹ̀kọ́ wọn ń yanṣẹ́lódì lọ́wọ́.

 Ó ní ìyanṣẹ́lódì ASUU ti ṣàkóbá lọ́pọ̀lọpọ̀ tí ìjọba sì gbọdọ̀ tètè mójúto ní kíákíá.

 Àrólé Oòduà ní ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀ tún jẹ́ ohun tí òun yóò máa gbàdúrà lé lórí kó le lọ ní ìrọ́wọ́rọsẹ̀ kí àláfíà le jọba ní orílẹ̀ èdè yìí.

 Ó fi ìdánilójú hàn wí pé gbogbo àdúrà tí òun bá ṣe náà ni yóò gbà nítorí kò sí ìgbà tí òun képe Ọlọ́run lásìkò ìgbélé náà tí àdúrà òun kìí gbá.

 Ní ọdọọdún ni ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń wáyé ní ìlú Ile Ife láti ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ tí Ọlọ́run dá ilé ayé.

 Lára àwọn ohun tí yóò wáyé níbi ayẹyẹ ti ọdún yìí ni Ilagun, Ojo Owode, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.