Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn afurasí olè tó jí mọ́tò Benz, fóònù gbé

Oríṣun àwòrán, police/FCT
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ti fi páńpẹ́ òfin gbé àwọn afurasí adigunjalè mẹ́ta kan ní agbègbè Gwarimpa, ìlú Abuja.
Àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni Shetima Abubakar, Yakubu Iliya àti Haruna Amadu.
Nígbà tó ń fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìlú Abuja, Josephine Adeh ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìnlélógún ni àwọn gba ìpè wí pé àwọn ìgárá ọlọ́ṣà ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Gwarimpa.
Adeh ní ago mẹ́rin ìdájí ni àwọn gba ìpè ọ̀hún pé àwọn olè náà wọlé àwọn ènìyàn tí wọ́n sì ń gba dúkìá àwọn ará àdúgbò tó ń gbé ibẹ̀.
Ó ní nígbà tí àwọn ọlọ́pàá Gwarimpa àti ti àwọn Life Camp ma fi dé ibi tí ìdigunjalè náà ti wáyé ni àwọn olè ọ̀hún fi ẹsẹ̀ fẹ.
Ó fi kun pé èyí ló mú kí àwọn ọlọ́pàá gbá tẹ̀lé àwọn olè náà tí wọ́n sì rí àwọn mẹ́ta mú nínú wọn.
Ní agbègbè Wuse 2 ni ọwọ́ ti tẹ àwọn olè náà nígbà tí ẹ̀ka ọlọ́pàá Maitama náà kún àwọn ọlọ́pàá yòókù lọ́wọ́ láti wá àwọn olè náà rí.

Oríṣun àwòrán, POLICE/FCT
Adeh ṣàlàyé pé ìwádìí fi hàn wí pé àwọn tí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ náà lé ní mẹ́wàá àti pé iṣẹ́ ti ń lọ lọ́wọ́ láti nawọ́ gán àwọn yòókù tó ti fẹsẹ̀ fẹ.
Ó tẹ̀síwájú pé lára ohun tí àwọn tí rí gbà lọ́wọ́ àwọn tí àwọn mú ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Mercedes Benz GLK 350 tó ní nọ́mbà ìdánimọ̀ GWA 740 FM èyí tí àwọn olè náà jí gbé ní ibi tí wọ́n ti jalè náà.
Àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n bá lọ́wọ́ wọn ni ẹ̀rọ kọ̀mpútà, fóònù àti àwọn dúkìá mìíràn tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n lọ jà lólè.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti ń fi ọ̀rọ̀ wá àwọn afurasí náà lẹ́nu wò, tí wọ́n yóò sì fojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí wọn bá ti parí.















