Olorì Badra, aya Aláàfin ṣe ìdárò bàbá rẹ̀, Alapinni tó papòdà

Oríṣun àwòrán, queenola2/Instagram
Bi ina ba ku, a fi eeru boju, bi ọgẹdẹ ba ku, yoo fi ọmọ rẹ rọpo, bi oloye ba si ku, yoo fi oloye silẹ lọ ni.
Ni ọjọ Aiku ana ni Alapinni ilu Oyo, Alhaji Abdul-Azeez Shehu ki aye pe o digbose lasiko aisan ranpẹ.
Wọn si ti sin Oloogbe naa nilana ẹsin Islam nile rẹ to wa nilu Oyo.
Amọ ọkan lara ọmọ Alapinni to di oloogbe ọhun tii tun se ọkan lara Ayaba Alaafin to waja, Olori Badra Adeyemi ti wa n sedaro baba rẹ to lọ.
"Mo gbadura pe ki Allah gba abọ baba mi"
Ninu ọrọ idaro to kọ soju opo ayelujara Instagram rẹ, Olori Badra ni “Inna lilahi waina ilehi rojiun.
Aapinni Oosha, n ko ni ọrọ to tọ lati sọ lasiko yii ju pe ki n gbadura si Alaah pe ko gba abọ rẹ.
Daddy mi.. Hmmm ko buru o.”
Ọrọ idaro yii si ni ọpọ ololufẹ Badra lori ayelujara ti n fesi si, ti wọn si n ki ku asẹyinde baba rẹ Alapinni to papoda.
Bẹẹ ba gbagbe, o ti to osu marun bayii ti Alaafin ilu Oyo, ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti dagbere faye.
Ti kan lara awọn Oyomesi to jẹ afọbajẹ nilu Oyo, Alapinni naa si tẹle.
Eyi si lo mu ki adinku ba iye awọn ọmọ igbimọ Oyomesi lati ori meje si marun.

Oríṣun àwòrán, queenola2/Instagram
Alapinni Oyo jáde láyé ní oṣù márùn ún tí Aláàfin wàjà

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọkan lara awọn afọbajẹ ni ilu Ọyọ, Alapinni ti ilu Oyo, Alhaji Abdul-Rasheed Shehu ti jade laye.
Iku Alapinni yii lo waye lẹyin oṣu marun un ti Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi jade laye.
Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ fun Alaafin Oyo, Bode Durojaye to fidi ọrọ naa mulẹ ni owurọ Ọjọ Aiku ni Alapinni jade laye.
Durojaye ni Alapinni Oyo, to si wa ninu igbimọ afọbajẹ Oyo ti wọn n pe ni Ọyọmesi, to jẹ igbimọ lni meje.
Amọ nitori iku rẹ, awọn Oyomesi naa ti ku mẹfa bayii.
Awọn eeyan ilu Oyo n se fọ Alapinni to lọ
O ni irọ ni Alapinni naa pẹlu Aṣipa ati awọn afọbajẹ to ku ti wọn di ipo Ọyọmesi mu.
Bakan naa ni ijọba ibilẹ ila oorun Oyo fi atẹjade sita lati kede iku Alapinni naa.
Ti wọn si fikun un pe wọn yoo sin ni ọsan Ọjọ Aiku oni to ku naa ni ile rẹ.
‘’Pẹlu ọkan to rẹwẹsi ni a fi kede iku Alapinni ti ilu Oyo, Oloye Agba, Alhaji Abdul-Rasheed Shehu ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹsan an, ọdun 2022.’’
‘’Isinku yoo si waye ni ile rẹ ni aago mẹrin irọlẹ ni ilana Musulumi’’
Lẹyin aisan ranpẹ ti wọn ko darukọ ni Alapinni naa jade laye.
Iroyin kan ti a ko tii le fidi rẹ mulẹ ni ọkan lara ọmọ Alapinni naa, Badira fẹ Ọba Lamidi Adeyemi ni igba aye rẹ.















