Wo ọkùnrin tó ní ìpèníjà ara, tó tún ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Adura ti ọpọ eeyan ma n se ni pe ki Oluwa ma gba ode ọsan lọwọ wa amọ to ba ti sẹlẹ, irẹwẹsi lo maa n ko ba ọpọ eeyan.
Amọ eyi ko ri bẹẹ fun ọkunrin kan to ni ipenija oju amọ to n fi ailera naa ja fun ẹtọ ọmọniyan.
Temitope Olujinmi Oyejobi to ni ipenija oju naa, ba BBC Yoruba sọrọ lori idi to se n ja fun ẹtọ ọmọniyan.
Bakan naa ni diẹ lara awọn eeyan ti Oyejobi ti ja fun ba BBC sọrọ lori ọna ti ẹni to ni ipenija oju naa n gba ran ilu lọwọ.
Koda, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi gan gbe ọrọ awọn eeyan yii lẹsẹ.
O si salaye fun BBC nipa bii ọkunrin to ni ipenija oju naa se maa n paara agọ ọlọpaa lati gbeja awọn araalu.
Wọn ko bi mi mọ ipenija oju, mo ti gbe iyawo ko to bẹrẹ - Oyejobi
Nigba to n salaye bi ipenija oju rẹ se bẹrẹ, Oyejọbi ni kii se pe bi wn se bi oun pẹlu ipenija oju ree amọ ọsan gangan aye oun ni isẹlẹ naa waye.
O ni ọdun 2012 lo bẹrẹ, ti oun si ti gbe iyawo, ti oun si wa mọto lọ silu Eko lati lọ ra ọja amọ ti oun ko le wa mọto naa pada wa sile mọ nitori pe oun ko riran.
Oyejobi ni dokita salaye fun oun pe aisan oju Glaucoma lo n yọ oun lẹnu lati bii ọdun mẹrin, ti oun ko si fura.
O ni aisan anaa lo fọ oju oun naa patapata.
“Iku baba mi lo jẹ ki n bẹrẹ iwa ijijagbara”
Nigba to n salaye ohun to sun de idi sise ijijagbara fawọn araalu, Oyejobi ni iku baba oun lo faa ti oun fi gbe igbesẹ naa.
“Baba mi ku ninu ijamba mọto lọna Sagamu si Ijebu Ode, tawọn ọlọpaa si mu ọkunrin kan pe oun lo wa mọto naa.
Ọkunrin naa si n pariwo pe oun ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa nitori pe mọto ti oun fi n sisẹ ti bajẹ, ti oun ko si wa ọkọ lọjọ ti ijamba naa waye.
Wọn fi ọkunrin naa si ahamọ ọgba ẹwọn laarin ọdun 2009 si 2013, ki oun to lọ gba silẹ, pe ki wọn fi silẹ, ko maa lọ.
Oyejobi ni lati akoko yii ni oun ti n ja fun ẹtọ awọn eeyan ti iya ba n jẹ.
O yẹ ka gbe oriyin fun akanda ẹda to n ran ẹlomiran lọwọ - Agbẹnusọ Ọlọpa l‘Ogun
Ọpọ awọn eeyan to ba BBC Yoruba sọrọ nipa oniruuru iranwọ ti Oyejobi ti se fun wọn lo kan saara si pe akọrin nii se.
Koda, wọn se alaye ọpọ iranwọ to ti se ati isẹ akin rẹ.
Fun iyalẹnu, koda, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun gan, Abimbola Oyeyemi kọrin rere ki akanda ẹda naa, ẹni to n gbe ija onija lai fi ti ipenija oju to ni se.
Oyeyemi salaye pe ileesẹ ọlpaa Ogun mọ Oyejobi bii isana ẹlẹẹta, to si maa n wa si ileesẹ ọlọpaa ni oore-koore lati wa gbeja ẹlomiran.
“Oyejobi maa n ba ọrọ araalu wa, tabi ko wa fi ẹjọ ọlọpa to ma huwa si araalu lọna ti ko yẹ wa, o si maa n gbọ alaye ta ba se.
O yẹ ka le maa gbe iru eeyan bayii larugẹ nitori pe ko fi ailera to n se han, o maa n se ojuse rẹ laarin ilu ni.
Ọpọ eeyan to ni ipenija ara bii tiẹ ni wn maa n tọrọ agbe loju popo amọ Oyejobi ko jẹ ki ipo to wa ko irẹwẹsi ba a.”






