Awakọ̀ èrò tíjọba ta ọkọ̀ rẹ̀ lo oṣù mẹ́ta lẹ́wọ̀n, ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́ta tún kú
Jandor àti Funke Akindele ṣe àbẹ̀wò sí ọkùnrin tíjọba ta ọkọ̀ rẹ̀, lo oṣù mẹ́ta lẹ́wọ̀n, tí ọmọ rẹ̀ sì tún kú

Oríṣun àwòrán, @officialjandor
Ọkunrin kan, Osinachi Ndukwe, ti ko alaye balẹ lori awọn adanwo to de ba nitori awọn igbesẹ aato oju popo ti ijọba ipinlẹ Eko gbe.
Ijọba ipinlẹ Eko lo lu awọn ọkọ mẹrinlelaadoje (134) ni gbanjo, to si ta wọn fawọn araalu, lara wọn si ni ọkọ ayọkẹlẹ kan, to jẹ ti Osinachi Ndukwe wa, eyi to fi n gbe ero loju popo.
Ijọba Eko lo n gba awọn ọkọ ero ati ti adani lọwọ awọn to ni wọn, ni kete ti wọn ba ti sẹ sawọn ofin to de igboke-gboko ọdọ nipinlẹ naa.
Lara awọn ijiya to wa fun awakọ to ba ta eyikeyi ninu awọn ofin irinna naa nipa ni pe ki ijọba ta mọto rẹ tabi ko lọ naju lọgba ẹwọn.
Amọ ni ti Osinachi, ijiya mejeeji oke yii lo gba, eyi to tun mu ẹmi ọmọdebinrin to bi lọ lasiko ti ijọba sọ pe o jẹbi ẹsun gbigba opopona ti ko tọ laarin ilu Eko
"Agbẹjọro kan lo ni ki n sọ fun adajọ pe mo jẹbi ẹsun tijọba fi kan mi"
Osinachi lasiko to n gbalejo oludije sipo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP , Dokita Abdul-Azeez Olajide Adediran ati igbakeji rẹ, Funke Akindele, lo sisọ loju ọrọ yii.
Gẹgẹ bi Osinachi se sọ fun Adediran, ti ọpọ eeyan tun mọ si Jandor ati igbakeji rẹ, o ni lootọ ni oun sọ nileẹjọ ti wọn gbe oun lọ pe oun jẹbi.
Jandor ati Akindele ni wọn lọ sile Osinachi lati ba oun ati aya rẹ kẹdun ofo mẹta to de baa naa, eyiun iku ọmọ rẹ obinrin, bi ijọba se lu mọto rẹ ni gbanjo ati ẹwọn osu mẹta to se.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, Osinachi ni “Agbẹjẹro kan lo ni ki n sọ fun adajọ pe mo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan mi.
O ni niwọn igba ti mo kuku ti n sọ tẹlẹ pe mo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan mi, ti mo si sọ bẹẹ fun adajọ.
Ọgba ẹwọn ni mo wa, ti ọmọdebinrin mi, ọmọ ọdun mẹta fi ku, ijọba tun ta mọto ero ti mo fi n sisẹ - Osinachi
Adajọ wa ni ki n lọ se ẹwọn osu mẹta, ti mo si lọ. Ọgba ẹwọn yii ni mo wa, ti wọn fi ni ọmọ mi obinrin n se aisan, amọ lẹyin ọsẹ meji, ni wọn pada sọ fun mi pe ọmọ naa ti ku.
Nigba ti mo pada de lati ọgba ẹwọn, mo lọ lati beere ọkọ mi ti mo fi n sisẹ amọ wọn sọ fun mi pe ọkọ ero naa kii se ti temi mọ, o ti di ti ijọba.
Mo wa n beere pe ki lo de lẹyin ti mo ti se ẹwọn osu mẹta, ti ọmọ mi obinrin tun ku, mo sọkun kikoro amọ se ni wọn ti mi sita kuro lẹnu ọna wọn.”
Osinachi ni aisi owo ti wọn yoo fi tọju ọmọ oun naa lo mu ko jade laye laipe ọjọ, ti oun si tun padanu ọkọ ti oun fi n sisẹ lẹyin ti oun ti se ẹwọn osu mẹta.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
O seese ki ọmọ Osinachi si wa laye, ka ni ijọba gba ki eeyan kan maa ba fi ọkọ rẹ sisẹ nigba ti oun gan wa lọgba ẹwọn - Jandor
Nigba to n fesi si awọn ọrọ abaninujẹ ti ọkunrin naa sọ, Jandor ni lootọ ni ojuse ijọba wa lati gbe ofin ro, ti wọn yoo si fiya jẹ ẹni yoowu to ba tapa si ofin.
Amọ o ni ohun ti awọn ko fara mọ ijiya ẹsẹ ti yoo gba irinsẹ ti awọn eeyan fi n sisẹ aje, lati ri ọwọ mu lọ sẹnu kuro lọwọ wọn.
O wa n beere pe ti ijọba ba ti gba mọto ero ti Osinachi fi n sisẹ lọwọ rẹ, bawo ni wọn se fẹ ko wa laye tabi ko bọ ẹbi rẹ?
“To ba jẹ pe o ti lo akoko to yẹ ni ọgba ẹwọn, ti wọn si gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ fun ẹnikan lati maa ba ọ fi sisẹ, o seese ki ọmọ rẹ si wa laye bayii.
A ba ọ kẹdun lori eleyi, amọ emi ati oludije igbakeji mi wa sibi lati wa wo ba se le seranwọ fun ọ lati mu idẹrun ati itunu ba isoro to n la kọja.”
Jandor sa salaye pe kii se pe oun n fara mọ pe ki awọn eeyan maa huwa ti ko tọ loju popo amọ o ni iwa ailaanu ni ki ijọba gba orisun ọrọ aje kuro lọwọ araalu fun ijiya ẹsẹ.
O fikun pe alaye ree ti isoro eto aabo se n buru si loju popo nitori bi ijọba se n gba orisun ọrọ aje araalu lẹnu wọn.

Oríṣun àwòrán, officialjandor/instagram
Ba se lu mọto 134 ni gbanjo ba ofin mu - Ijọba Eko
Wayi o, ijọba ipinlẹ Eko ti wa salaye idi to fi ta ọkọ to to mẹrinlelaadoje ti wọn gbẹsẹ le nitori bi awọn awakọ se tapa si awọn ofin to de eto irinna nipinlẹ naa.
Igbesẹ naa, eyi to ti fa awuyewuye lawọn oju opo ayelujara, ti ọpọ eeyan si ni igbesẹ ijọba naa buru jai, to si ku diẹ kaato.
Awọn eeyan to ni awọn mọto naa, ni ọpọ fidio to wa lori ayelujara se afihan wọn, bi wọn se n gbe ara asanl nigba tijọba Eko n lu gbanjo le awọn ọkọ naa lori fun tita.
Amọ amugbalẹgbẹ fun gomina Babajide Sanwo-Olu feto isẹ iroyin igbalode, Jubril Gawat, ti wa salaye idi tijọba fi se bẹẹ loju opo Twitter rẹ.
Gawat, ninu akọle ikede kan to pe ni “ootọ ọrọ nipa igbesẹ bijọba ipinlẹ Eko se n lu gbanjo” ni eyi wa nibamu pẹlu ofin.
Gawat ni ọpọ awọn mọto ti wọn gbẹsẹle naa lo jẹ ko san owo itanran lasan amọ se ni awọn to ni wọn pa wọn ti sọdọ ijọba, tijba ko si ni nnkan to fẹ fi wọn se ju ko lu wọn ni gbanjo lọ.
“Ọpọ awọn kọ naa lo gba ọna ti ko yẹ, ti wọn si gbẹsẹ le wọn amọ awọn awakọ miran sa lọ nitori wn ko fẹ koju ileẹjọ.
Igbesẹ lilu awọn mọto naa ni gbanjo ti igbimọ amusẹya n se lo wa lati fi ewe ọmọ mọ awọn araalu leti pe ki wọn ye tapa sawọn ofin to de eto irinna loju popo.”
Gawat ni oun lero pe igbesẹ naa yoo jẹ arikọgbọn fun awọn awakọ to kundun asa yii nitori ofin ko mọ oju ẹnikẹni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò gbé Àbá Ìṣúná ọdún 2023 ló sílè ìgbìmọ̀ Aṣofin

Oríṣun àwòrán, SPEAKER GBAJAMILA /FACEBOOK
Olori ile aṣoju sofin orilẹ-ede yii Femi Gbajabiamila ti kede pe Aare Muhammadu Buhari ko ni pẹ́ gbe aba isuna 2023 wa.
O ni pe ninu ọsẹ akọkọ, osu Kẹwaa yoo gbe aba isuno orilẹ-ede yii ti ọdun 2023 wa siwaju ile igbimọ asofin .
Gbajabiamila ni trillionu okandinlogun le die naira ni Aare Muhamadu Buhari yoo gbe wa si ile igbimo asoju sofin
Gbajabiamila sọ iroyin yii nigbati o se abewo sii ibi atunṣe ton nlo lọwọ si gbogon ile igbimọ aṣojú sofin eyi ti awọn agbasese yoo paari nipari osu kejo ọdun 2023

Oríṣun àwòrán, SPEAKER FEMI GBAJABIAMILA/FACEBOOK
Oni atunse ile igbimọ aṣoju sofin orilẹ-ede yii yo wa ni ibamu pelu awọn ile igbimọ asofin ka kiri agbaye.
O ro awọn agbasese naa lati yaara si iṣẹ,
Atunṣe ile aṣoju sofin yoo paari ninu osu kejo ọdun ton bo.












