Makinde pè fún ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ Ayu gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kí àláfíà lè jọba

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe alaye wi pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP gbudọ fi gbogbo awọn koko ọrọ ti wọn fi n ṣe ipolongo idibo sinu gbogbo ṣiṣe wọn bi o ba wu ẹgbẹ naa lati bori ninu eto idibio ọdun 2023.
Lasiko to n sọrọ nibi ipade apero awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti o waye l'Ọjọru niluu Ibadan,
Makinde ni, "bi ọmọ iya meji ba wo inu iyẹwu lọ, ti wọn si rẹrin jade, o tumọ si wi pe wọn ko ba ara wọn sọ ootọ ọrọ".

O ni awọn ipenija to n koju ẹgbẹ oṣelu naa ko kọja ohun ti awọn alakoso ẹgbẹ naa le yanju ti ohun gbogbo yoo si pada si ipo. Makinde ni awọn adari ẹgbẹ gbudọ ṣe atunto lẹyin ti alaga to n ṣe akoso lọwọ bayii ba kọ iwe fi ipo silẹ, ki awọn ọmọ ẹgbẹ ti o n bẹ ni ẹkun guusu naa le ni anfani lati ni aṣoju ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Gomina ipinlẹ Ọyọ fi kun ọrọ rẹ wi pe iṣọkun gbudọ waye ninu ẹgbẹ oṣelu naa ki wọn to le mu ki iṣọkan waye lorilẹede Naijiria.

Atiku fèsì fún Makinde lórí ọ̀rọ̀ yíyọ Ayu pe...
Ninu ọrọ tiẹ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri ti o tun jẹ oludije si ipo aarẹ orilẹede yii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti daa pada fun Makinde.
O fesi wi pe ipe fun ikọwefiposilẹ alaga ẹgbẹ oṣelu naa tabi ẹnikẹni to n ṣoju ẹgbẹ naa le ṣeeṣe nipase ofin ẹgbẹ oṣelu naa,
pẹlu alaye wi pe awọn igbese ti ko ni atilẹyin ofin tẹlẹri le ṣeeṣe bi ẹgbẹ naa ba tun ofin wọn kọ.
Ọpọlọpọ awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo pejupesẹ si gbọngan nla Theophilus Oladipo Ogunlesi ti apero naa ti waye ladojukọ UCH.
Lara wọn ni oludije fun igbakeji aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa ti o tun jẹ gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Awọn gomina tẹlẹri naa ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.
Lara wọn ni gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Oyinlọla Ọlagunsoye ti ipinlẹ Ọṣun, Ayọ Fayoṣe ti ipinlẹ Ekiti, Muazu Babangida ti ipinlẹ Niger, Oluṣegun Mimiko lati ipinlẹ Ondo.
Lara awọn alejo pataki ti o darapọ mọ ipade naa ni Sẹneto Dino Melaye, Sẹneto Abiọdun Olujimi.
Bakan naa ni a ri Oludije si ipo gomina ipinlẹ Eko, Olajide 'Jandor' Adediran ati Funke Akindele to n dije gẹgẹ bii igbakeji rẹ.
Oludije si ipo gomina ipinlẹ Ogun, Oladipupo Adebutu naa ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.















