William Ruto: Wo ipa tí ó ṣeéṣe kí ẹ̀sìn kó nínú ìṣèjọba ààrẹ Kenya tuntun

Ruto nibi to ti n gbadura nile ijọsin

Oríṣun àwòrán, DP OFFICE

    • Author, Evelyne Musambi
    • Role, BBC News, Nairobi

William Ruto ti wọn yoo bura wọle sipo fun lọjọ Iṣgun ni aarẹ orileede naa akọkọ to jẹ onigbagbọ ajihinrere to si ṣeeṣe ki o ma ko iyan ẹsin kere tori pe o kopa ribi ninu aṣeyọri rẹ.

Ẹni ọdun marundinlọgọta yi kii fi igbagbọ rẹ bo to si j ẹni ti ko dakẹ lori ọrọ iwa akọsakọ ati oyun ṣiṣẹ to jẹ nkan to le jẹyọ lasiko iṣejọba rẹ.

Lọpọ igba ni Ruto a maa fi ẹsẹ Bibeli kin ọrọ rẹ lẹyin, a maa gbadura lode koda Ruto maa n bu sẹkun nita gbangba.

Lasiko ipolongo ibo awọn alatilẹyin rẹ a maa fi ṣe yẹyẹ pẹlu orukọ ''igbakeji Jesu''- awọn alatilẹyin rẹ ko binu ti wọn si tẹwọ gba orukọ yi.

Igbesẹ akọkọ to gbe nigba ti wọn kede pe o bori ni ile ẹjọ to gajulọ ni pe o kunlẹ pẹlu iyawo rẹ ati awọn ti wọn jijọ duro ti wọn si gbadura ninu iyara.

Koda ọgbni Ruo ati iyawo rẹ ti kọ ile ijọsin kekere kan sinu ile wọn to wa ni agbegbe Karen ni olu ilu Kenya, Nairobi.

Olori ẹlẹsin musulumi kanna tun wa lati gbadura ninu ile Ruto lẹyin ti wọn kede rẹ pe o jaweolubori.

Eyi fi han pe toun ti pe o jẹ ẹlẹsin Kristẹni, o n gbero lati jẹ baba fun gbogbo ẹlẹsin nilẹ naa.

Lọpọ igba irẹpọ wa laarin awọn ẹlẹsin ni Kenya ti pupọ awọn musulumi si wa lara awọn alatilẹyin Ruto.

Biṣọọbu David Oginde ti ijọ Evangelical Alliance of Kenya sọ pe awọn lero pe ijọba Ruto yoo duro fun ''iwa daada ti yoo si fọwọ fun pe Kenya jẹ awujọ ẹlẹsin''

Orileede Onigbagbọ ni Kenya jẹ

Igbagbọ n kopa gidi n iKenya. Adajọ agba ilẹ naa Martha Koome ṣapejuwe idajọ ijaweolubori Ruto gẹgẹ bi ''iṣẹ ọwọ Ọlọrun'' dipo iṣẹ ọwọ ile ẹjọ.

Nigba to wa ni igbakeji, ipa ẹsin to wa lara Ruto lapa lori aarẹ Uhuru Kenyatta to jẹ ọmọ ijọ Katoliiki ni saa kini wọn ni ijọba.

Ni paapa nigba ti wọn gbiyanju lati fọ ara wọn m niwaju ile ẹjọ agbaye lori ẹsun iwa ikọlu ti wọn fi kan wọn tori wahala to tẹyin idibo ọdun 2007 bọ

Awọn mejeeji ko sinmi lati maa ṣabwo sawọn ile ijọsin nipa gbigba adura ki araalu baa si le kaanu wọn lasiko igbẹjọ.

Igbesẹ yi so eso rere nitori wọn pada wọgile sun ti wọn fi kan Kenyatta ldun 2014 ti adajọ si da ẹsun ti wọn fi kan Ruto nu lọdun 2016.

Mosalasi kan to wa laarin opopona Mombasa si Nairobi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn musulumi ni ẹlẹsin to tobi julọ ṣikeji ni Kenya

Ruto ati iyawo rẹ ni wọn jijọ jẹ onihinrere

Idile onihinrere ni wọn biRuto si tawọn ileeṣẹ iroyin labẹle si gbe aworan igba ọdọ nibi to ti jẹ Pasitọ sita.

Iyawo rẹ a maaa ṣeto adura loore koore ti Ruto si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi igi lyin ọgba rẹ to kopa ninu aṣeyọri rẹ lagbo oṣelu.

Ruto ati iyawo Rachel ninu aworan kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ero iyawo William Ruto ati iyawo papọ nipa igbagbọ wọn

Koda o ri ọwọ mu daada nipa bi iyawo igbakeji rẹ Rigathi Gachuga,arabinrin Dorcas ṣe ffinti nidi iṣ banki to si ti wa di Pasitọ.

Ni Kenya, ida 85% jẹ Kristẹni,ida 33% jẹ Protestant,ida 21% Catholic ida 20% jẹ onihinrere tawọn ṣọọsi alabẹle si jẹ ida 7%.

Ida mọkanla awọn eeyan ilẹ naa si jẹ Musulumi gẹgẹ bi a ṣe ri ka ninu eto ikaniyan to waye lọdun 2019.

Aworan awọn ẹlẹsin Kristẹni ni Nairobi lasiko ajọdun Good Friday lọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Krisni ni ọpọ ọmọ orileede Kenya

Ireti wa pe arakunrin Ruto yoo fẹsẹ rẹ rinlẹ lori ọrọ akọsakọ ṣaaju abẹwo akọwe ijọba igba kan rii lAmẹrika John Kerry.

Ruto ti sọ fun ijọ ile ijọsin kan ṣaaju pe ''Kenya jẹ ilẹ ta ti n sin Ọlọrun.Ko si aaye fun iwa akọsakọ tabi abosabo''

Ninu ifọrọwanilnuwo kan to ṣe pẹlu CNN lẹyin to jaweolubori, o sọ pe ''oun ko fẹ sọ ọrọ kekere di ranto tori naa bi ọrọ ibalopọ akọ si akọ ba di nkan nla lọdọ awọn eeyan Kenya, wọn yoo gbe igbesẹ le lori''

Ọgbẹni Ruto ni atilẹyin to fẹsẹ rinlẹ laarin awọn musulumi nitori awọn naa kọri si ibi kanna pẹlu rẹ lori akọsakọ ati ọrọ oyun ṣiṣẹ.

O ri iranwọ lọdọ wọn lasiko idibo nigba ti ọpọ olori musulumi to wa ninu ẹgbẹ United Democratic Movement ya kuro lẹyin Raila Odinga ti wọn si ran Ruto lọwọ lati jaweolubori.

Election branding
Election branding